Faith Adebọla
Ẹka Ọtẹlẹmuyẹ tileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko lawọn ti bẹrẹ iwadii lati mọ bi iku ojiji ṣe mu Bassey Asuquo lọ, ọkunrin ẹni ogoji ọdun to doloogbe sinu otẹẹli kan lagbegbe Ipaja, lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii.
ALAROYE gbọ pe apoogun oyinbo (Phamacist) lọkunrin ọhun. Ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ni wọn loun ati ọmọbinrin aṣẹwo kan lọọ gba yara lotẹẹli kan ta a forukọ bo laṣiiri to wa lẹba ọna Akẹsan, ni Ẹgan, lagbegbe Ipaja lati gbadun ara wọn.
Ọkan lara awọn oṣiṣẹ otẹẹli naa to wa lẹnu iṣẹ alẹ lọjọ yii ṣalaye fawọn ọlọpaa pe oloogbe ọhun ati sisi ẹ kọkọ jokoo ni ibi ti wọn ti n muti lotẹẹli naa, wọn mu waini, wọn ṣe faaji. Nnkan bii aago mọkanla ni wọn too gba inu yara wọn lọ.
Nigba to dọwọ idaji ni aṣẹwo jade ni tiẹ, wọn lo sọ pe kọsitọma oun ṣi n sun ninu yara, ṣugbọn lẹyin bii wakati kan ni wọn laṣẹwo naa tun tẹ otẹẹli naa laago, o ti fi nọmba aago tiẹ pamọ, lo ba sọ fun ẹni to ba a sọrọ pe ki wọn lọọ wo maanu toun pẹlu rẹ jọ sun mọju yẹn o, o lo da bii pe nnkan kan n ṣe e, oun ko si mọ ohun to n ṣe e o.
Wọn lobinrin naa sọ pe bawọn ṣe n ṣere ifẹ lọwọ loun ri i pe mimi Bassey ti yatọ, o n mi gulegule, loun ba kuro labẹ ẹ, oun si ṣaajo ẹ, ṣugbọn ko sọrọ kan, o si ti rẹ ẹ, o ti n rọ jọwọrọ.
Nigba tawọn ọlọpaa debẹ, wọn lawọn kiyesi i pe niṣe lo da bii pe nnkan kan ṣe ọkunrin lagọọ ara lojiji, ati pe bo ṣe nawọ, o jọ pe o fẹẹ mu inhaler rẹ, ṣugbọn ti ko ṣee ṣe fun un.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Bala Elkana, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ni awọn ti gbe oku ọkunrin naa lọ sile iwosan fun ayẹwo, wọn si ti fi pampẹ ofin gbe awọn oṣiṣẹ meji ti wọn wa lẹnu iṣẹ nigba tiṣẹlẹ naa waye