Ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ilẹ yii (DSS) ti mu ọga ajọ to n gbogun ti ṣiṣe owo ilu baṣubaṣu (EFCC), Ibrahim Magu.
ALAROYE gbọ pe wọn mu Magu lori dukia mẹrin to ni lọna aitọ, ati pe o n ko owo pamọ soke-okun.
Olu-ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ to wa ni Aso Drive niluu Abuja la gbọ pe wọn gbe e lọ, iyẹn lẹyin to ti kọkọ wa ni ọfiisi ileeṣẹ naa ni Wuse II, niluu kan naa.
Gẹgẹ bi iroyin to n lọ, iṣẹlẹ naa ko ṣẹyin iwadii awọn DSS lọdun 2016, eyi to sọ pe Magu n gbe ile nla kan towo ẹ to miliọnu lọna ogoji naira ti Ọgagun-fẹyinyi Umar Mohammed to jẹ adari nileeṣẹ ọmọ-ogun ori omi tẹlẹ ra fun un.
Bakan naa la gbọ pe ẹka to n ṣakoso ileeṣẹ ọlọpaa, Police Service Commission, sọ pe o jẹbi ẹsun aṣemaṣe kan an lọdun 2010.
Ajọ DSS ko ti i sọrọ lori iṣẹlẹ yii, bẹẹ ni gbogbo awọn to ti gbọ nipa ọrọ naa n reti abajade rẹ.
Ọjọ kẹsan-an, oṣu kọkanla, ọdun 2015, ni Magu di adele ọga-agba EFCC, ipo adele lo si wa di akoko yii.