Stephen Ajagbe, Ilọrin
Iroyin to tẹ wa lọwọ lọsan-an oni, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni pe Igbakeji Gomina Kwara, Kayọde Alabi ati rẹ, Abilekọ Abieyuwa Alabi, ti ko arun Korona.
Atẹjade kan ti akọwe iroyin to tun jẹ alukoro igbimọ to n gbogun ti arun naa nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Rafiu Ajakaye, fi sita sọ pe awọn mejeeji lo ṣe ayẹwo to fi han pe wọn ti lugbadi arun naa, wọn si ti wa nibi ti wọn ti n gba itọju.
Ajakaye ni awọn eleto ilera ti n tọpinpin gbogbo awọn to ti ni ibaṣepọ pẹlu awọn mejeeji lẹnu ọjọ mẹta yii.
Ijọba waa gbadura ki Ọlọrun fun tọkọ-taya naa lalaafia.
Alabi ni alaga igbimọ amuṣẹya to n gbogun ti arun Koronafairọọsi nipinlẹ Kwara.