O ṣẹlẹ! Ile-ẹjọ paṣẹ pe Adeleke ko gbọdọ gbe ọpa aṣẹ fun Arèé ti ilu Iree

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ile-ẹjọ giga tipinlẹ Ọṣun, ti paṣẹ pe Gomina Ademọla Adeleke ko gbọdọ fun Aree tuntun to yan, Ọmọọba Muritala Oyelakin, ni satifikeeti, bẹẹ ni ko gbọdọ gbe ọpa aṣẹ fun un.

Nigba ti Onidaajọ M. O. Awẹ, n gbọ ẹjọ kan ti Ọba Rapheal Pọnnle Ademọla gbe lọ siwaju rẹ lo sọ pe ijọba Ọṣun ko gbọdọ gbe igbesẹ kankan lori ọrọ naa titi digba ti ile-ẹjọ yoo gbọ ẹjọ to wa niwaju rẹ.

Tẹ o ba gbagbe, ijọba gomina ana l’Ọṣun, Adegboyega Oyetọla, lo fi Ọba Ademọla jẹ, ṣugbọn ni kete ti wọn bura fun Gomina Adeleke lo paṣẹ pe ki ọba naa lọọ rọọkun nile, o si gbe igbimọ kan kalẹ lati ṣewadii iyansipo rẹ.

Ọba Ademọla fori le kootu lati ka ijọba lọwọ ko, o si ku diẹ kile-ẹjọ gbe idajọ kalẹ lawọn oṣiṣẹ kootu Ọṣun daṣẹ silẹ fun ọpọlọpọ oṣu.

Ninu iwe ipẹjọ to ni nọmba HOS/20/2024, ni Ọba Pọnnle ti wọ Gomina Adeleke, kọmiṣanna fun ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ, ijọba ibilẹ Boripẹ, Ọṣọlọ ti ilu Iree, Aogun ti ilu Iree, Inurin ti ilu Iree, Jagun ti ilu Iree ati Ọmọọba Muritala Oyelakin lọ si kootu.

Ṣugbọn lopin ọdun to kọja ni Gomina Adeleke kede pe iyansipo ọba naa ko ba ilana oye jijẹ ilu naa mu, o si paṣẹ pe ki igbesẹ tuntun bẹrẹ, bẹẹ ni wọn kede Ọmọọba Oyelakin gẹgẹ bii Aree tuntun lọdun yii.

Nigba ti wọn pe ẹjọ yii ni kootu, awọn olujẹjọ ko yọju, bẹẹ ni awọn agbẹjọro wọn ko wa.

Lẹyin atotonu agbẹjọro olupẹjọ, Onidaajọ Awẹ paṣẹ pe ijọba ko gbọdọ gbe ọpa aṣẹ fun Ọmọọba Oyelakin, bẹẹ ni ki ohun gbogbo wa bo ṣe wa tẹlẹ niluu titi di ọjọ kẹjọ, oṣu Karun-un, ọdun yii, ti ile-ẹjọ yoo sọrọ nipa ẹjọ iwaju rẹ.

Leave a Reply