Faith Adebọla
Wahala aabo to mẹhẹ lorileede yii ti gbọna mi-in yọ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii pẹlu bawọn afurasi adigunjale lọọ fọle Olori awọn oṣiṣẹ ọba nileeṣẹ Aarẹ, Ọjọgbọn Ibrahim Gambari, niluu Abuja.
Ile tọkunrin naa n gbe lo wa ni opopona keji si ile ijọba apapọ, iyẹn Aso Rock Presidential Villa, ni Abuja, olu-ilu ilẹ wa.
Wọn lawọn afurasi adigunjale naa gba ọna ẹyin wọnu ile Gambari, wọn si da ọpọlọpọ nnkan ru ninu ile naa, wọn tun wọ awọn yara kan nibẹ, a gbọ pe owo ti wọn o ti i sọ iye ẹ ati awọn dukia mi-in ni wọn ji ko lọ.
Oluranlọwọ pataki fun Aarẹ lori eto iroyin, Mallam Garba Shehu, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O sọ lori atẹ ayelujara, ikanni abẹyẹfo (tuita) rẹ pe loootọ lawọn kan gbiyanju lati fọle Gambari laaarọ ọjọ Aje yii, ṣugbọn o ni wọn o ri ẹru ko, bo tilẹ jẹ pe wọn wọle ohun.
Garba, ti ile rẹ ko fi bẹẹ jinna si ti Gambari lopopona kan naa sọ pe awọn agbofinro ti bẹrẹ iwadii lẹkun-unrẹrẹ lori iṣẹlẹ yii, ati pe ko si idi fawọn araalu lati ko ọkan soke lori iṣẹlẹ ọhun.