Nibo ni Buhari fẹẹ sa gba!
Ọrọ Aarẹ Muhammadu Buhari ati awọn eeyan ti wọn wa lẹgbẹẹ rẹ ti wọn n ba a ṣiṣẹ, ọrọ awodi oke ti i ṣe bi ara ilẹ ko ri oun ni. Nigba ti ẹyẹ awodi ba fo soke lala, yoo ro pe awọn eeyan ti wọn wa ni isalẹ ilẹ ko ri oun, bẹẹ atinu ati ẹyin rẹ lawọn eeyan n wo yii. Olokun-un-run ti wọn ni ko ṣe too, yoo si maa pariwo kiri pe oun ko le ṣe too too too. Awọn aṣofin ni awọn fẹẹ ri Buhari, wọn o pe e fun iku, wọn ko pe e fun arun, wọn ni ko waa ṣalaye ohun to n ṣe nipa ọrọ awọn apaayan Boko Haram to ti fẹẹ sọ Naijiria di olu ilu wọn ni. Ko kuku si ẹni ti ko mọ aburu ti awọn Boko Haram yii n ṣe, paapaa nilẹ Hausa, nibi ti Buhari funra rẹ ti wa. Wọn ko paayan ni ẹyọ kọọkan bayii mọ, ogoogun, ọgbọọgbọn lo ku ti wọn n paayan, ọrọ naa si le debii pe Sultan, ọba ilu Sokoto, funra rẹ pariwo sita pe awọn afẹmiṣofo Boko Haram ati awọn janduku mi-in ti gba gbogbo ilẹ Hausa tan, ọsan gangan ni wọn n gbe ibọn kiri, ti wọn n da awọn eeyan lọna, ti wọn si n ṣe bo ṣe wu wọn kiri. Ohun ti awọn aṣofin tori ẹ pe Buhari niyẹn. Ko si orilẹ-ede ti ki i ti i si wahala, idaamu kan tabi omi-in, bi orilẹ-ede kan ba ti to naa ni wahala wọn i to. Bi ko jẹ ti wahala ọrọ-aje wọn, yoo jẹ ti iru awọn janduku tabi afẹmiṣofo, o si le jẹ wahala laarin awọn oloṣelu ara tiwọn gan-an ni. Ijọba to ba waa dara ni yoo mọ bi yoo ṣe yanju iṣoro bẹẹ. Ọkan pataki lara ọna ti ijọba si maa n lo ni ki olori ijọba bẹẹ bọ si gbangba, ko ṣalaye ohun to ba n ṣẹlẹ gan-an fawọn araalu, nitori bi awọn araalu ba ti mọ bi ọrọ yii ti ri, ọkan wọn yoo balẹ diẹ, awọn naa yoo si mọ ọna ti wọn yoo fi ran ijọba lọwọ. Agaga bo ba ṣe niwaju igbimọ aṣofin orilẹ-ede bẹẹ ni wọn yoo ti ṣalaye ohun to ba ba orilẹ-ede wọn, anfaani nla ni fun olori ijọba bẹẹ, nitori bo ti n fi ọwọ kan tẹ pẹpẹ ọrọ faraalu, bẹẹ ni yoo maa fi ọwọ kan ṣalaye fawọn aṣofin, a ṣe pe araalu ati awọn aṣofin wọn yoo jọ mọ ohun to n lọ sọwọ kan naa ni. Ohun ti ko jẹ ki eeyan le ronu daadaa lori idi ti olori orilẹ-ede tiwa ko fi yọju sawọn aṣofin ilẹ wa niyi o. Wọn ni ki Buhari wa, oun ati awọn eeyan rẹ bẹrẹ si i lọ irọ lọrun, wọn ni ko yẹ ko lọ sibẹ, nitori ofin kan wa, idi kan wa, ọrọ kan wa nilẹ, awọn kan fẹẹ ṣe yẹyẹ rẹ, ati ọpọlọpọ ọrọ raurau bẹẹ ti ko mu laakaye kankan dani. Ki lo tun le buru ju ki awọn kan maa pa awọn ọmọ Naijiria bii ẹni pẹran bayii lọ! Ofin wo lo si wa to ṣe pataki to ju ofin ti yoo daabo bo awọn ọmọ orilee-de yii lọ. Dajudaju, nnkan kan wa ti awọn eeyan yii n fi pamọ, o nidii ti wọn o fi fẹ ki Buhari jade si gbangba. Ṣugbọn ẹlẹlẹya kan bayii ni gbogbo wọn. Abi nigba ti wọn pe Buhari ko wa si ile-igbimọ aṣofin ti ko wa, ti awọn eeyan si bẹrẹ si i sọ pe nitori ara rẹ ti ko ya ni, ti awọn mi-in n sọ pe o ti ku ni, ki i ṣe oun lo wa ni Aso Rock, ti awọn ti wọn maa n mura fun un bii eegun waa sare ko ẹwu si i lọrun, ti wọn ni ko niṣo ni Daura, ko lọọ ki wọn ni Katsina, ki gbogbo aye le ri i pe alaafia lo wa, kinni kan ko ṣe e. Kin ni itumọ iyẹn! Wọn ni yoo lo ọsẹ kan ni Katsina fun isinmi! Iyẹn ni pe iṣẹ Buhari ti ko jade sita lati ọjọ yii ti waa pọ to bẹẹ to fi nilo isinmi. Ẹtan ni gbogbo ẹ, gbogbo awọn ti wọn si n tan awọn ọmọ Naijiria jẹ bayii, Ọlọrun naa yoo tan wọn jẹ tiran-tiran, tẹbi-tẹbi tiwọn naa, nitori gbogbo ohun ti wọn n ṣe yii, ti wọn ba ro pe awọn le ṣe e gbe, wọn n tan ara wọn ni. Fun ti Buhari to si n sa kiri, ẹgbẹrun saamu lọrọ rẹ, ẹgbẹrun saamu ko saa ni i sa mọ Ọlọrun lọwọ, wọn yoo mu un gbẹyin naa ni. Wọn ni kinni yii kinni ẹ ni, o ni o n lọ soko, koda ki o lọ si odo, ṣe ti o ba de, o ko ni i ba a ni. Bi Buhari ko ba ṣe ohun to yẹ ko ṣe, wahala Boko Haram yoo fa oun naa si ibi ti ko fẹ, nitori wahala naa ko ni i lọ boun naa ko ba ṣe ohun to yẹ ko ṣe. Ẹyin tẹ ẹ ba moju ẹ, tẹ ẹ ba ri i kẹ ẹ tete sọ fun un.
Tabi ẹyin naa ko ri ohun to ṣẹlẹ ni Katsina
Lati sọ fun Aarẹ Muhammadu Buhari pe ko nibi kan to fẹẹ sa lọ, nitori ọrọ Boko Haram to n tori ẹ sa kiri ko ni i lọ bẹẹ, lọjọ to wọ ilu rẹ ni ipinlẹ Katsina, ọjọ naa ni awọn afẹmiṣofo yii ya lọ si ileewe nla kan to jẹ tawọn ọkunrin nikan. Ileewe girama Government Science Secondary School, ni ilu Kankara, ni Katsina. Awọn ọmọ bii irinwo, 400, lawọn Boko Haram yii si ko lo lẹẹkan. Gomina funra ẹ, Gomina Masari, sọ pe awọn ṣi n wa awọn ọmọ to le ni ọọdunrun (300) ti awọn ko mọ ibi ti wọn wa rara. Awọn Boko Haram wa ninu ileewe yii fun akoko to le ni wakati kan daadaa, nigba ti wọn si ṣe ohun ti wọn fẹẹ ṣe tan lawọn ṣọja Naijiria too de, wọn ko si le da awọn afẹmiṣofo yii duro titi ti wọn fi ko awọn ọmọ ti wọn fẹẹ ko lọ lọ. Ọrọ naa dun-un-yan, o si ba ni ninu jẹ gan-an. Idi ni pe koda, awọn ti wọn ki i ṣe ologun, ti wọn ko si jẹ olori ṣọja mọ pe ko yẹ ki awọn ologun wa ti wọn ni awọn n gbogun ti Boko Haram fi iru awọn ileewe bayii silẹ, ileewe giga to jẹ kidaa awọn ọkunrin, ati ileewe giga to jẹ kidaa awọn obinrin. Idi ni pe gbogbo awọn olori ologun lo mọ pe ko si bi awọn Boko Haram yii ti le pọ to, wọn yoo nilo lati maa ko awọn ọmọde ọkunrin mọra si i, ki wọn le sọ wọn di Boko Haram, ki wọn yi wọn ni ọpọlọ pada, ki awọn naa si maa fi ẹmi awọn eeyan ṣofo, gẹgẹ bii awọn ti wọn waa ko wọn. Ko si ohun ti i tete jẹ ki wọn ṣẹgun awọn ọta loju ogun ju nigba ti awọn ọta bẹẹ ko ba ni ọmọ ogun wẹwẹ ti wọn yoo lo mọ. Ọna kan lati ri awọn ọmọ ogun ni lati lọ si ibi ti awọn ọmọdekunrin ba pọ si bayii, ki wọn ji wọn ko, wọn yoo si di afẹmiṣofo laipẹ rara. Lọna keji, ibi ti obinrin ọmọde ba pọ si, awọn ọlọtẹ bayii a maa lọ sibẹ lati lọọ ji awọn ọmọbinrin ko fun awọn jagunjagun wọn, ki wọn le maa fi ipa ba wọn sun, ki wọn le maa ṣe abiyamọ fun wọn, ọmọ ti wọn ba si bi, ọmọ Boko Haram ni. Awọn ọdẹ ibilẹ gan-an mọ eyi, ka ma ti i sọ awọn olori ologun ilẹ wa. Ṣugbọn ki la maa ri, ni ipinlẹ ti Aarẹ ile wa jokoo si pẹlu awọn ẹṣọ loriṣiiriṣii, awọn Boko Haram lọ sibẹ, wọn si ko awọn ọmọkunrin to pọ to bẹẹ yẹn lọ. Nibo ni awọn olori ologun yii wa? Nibo ni awọn ọga ṣọja ti wọn n sọ pe awọn ti ṣẹgun Boko Haram wa? Nibo ni awọn ẹnu-n-ja-waya ti wọn ni ko si Boko Haram wa gan-an? Ṣe o digba ti awọn Boko Haram ba ji Buhari funra ẹ gbe kawọn eeyan yii too mọ pe ewu wa lọrun wa ni, ati pe Boko Haram ti fẹẹ gba Naijiria mọ wọn lọwọ. Abi iru ki leleyii Ọlọrun Ọba. Ki Buhari le awọn olori awọn ologun yii lọ, ko gba ipo yii kuro lọwọ wọn, ko si fi awọn mi-in si i, ki awọn yii le lo ẹjẹ tuntun lati fi ba wa le Boko Haram jinna, ki gbogbo ọmọ Naijiria le ni isinmi to peye.
Ẹ da Wọle Ṣoyinka lohun, ta lolori wa ni Naijiria o
Ti eeyan ba fẹẹ wo ọrọ ti agba ọnkọwe nni, Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka, sọ laipẹ yii, ọrọ Naijiria yoo si su tọhun patapata. Nibi ifilọlẹ iwe kan ti Ọjọgbọn yii lọ niluu Ibadan lọsẹ to koja, Ṣoyinka ni nigba ti eeyan ba wo gbogbo ohun to ṣẹlẹ si wa lọdun yii ni Naijiria, yoo ṣoro ki onitọhun too gba pe ẹni kankan wa rara to jẹ olori Naijiria, tabi to n dari Naijiria sibi kan. Lọrọ kan, ilu ti ko lolori la n gbe. Bawo ni ilu yoo ṣe tobi to bayii ti ko ni i lolori! Awọn eeyan ti wọn ba gbọ, ti wọn ko si farabalẹ tumọ ọrọ naa, wọn yoo ro pe asọdun lasan ni Ṣoyinka n sọ ni. Ṣugbọn ẹni to ba mọ ọjọgbọn yii, to si mọ ohun ti oju rẹ ti ri ni Naijiria yii kan naa lati aye awọn Gowon ti wọn ti n ju u sẹwọn, titi de aye awọn Shagari ti wọn jọ n kọrin owe bu ara wọn, ati aye Sani Abacha ti wọn n wa ẹmi rẹ kiri, eeyan yoo mọ pe ojo ti n pa igun bọ, ọjọ ti pẹ, ọrọ ti Ṣoyinka ba sọ, lati agodo imọ lo ti jade. Ṣe eeyan le sọ pe orilẹ-ede yii ni olori loootọ ni! Nibi ti awọn Fulani ti n jiiyan gbe lojoojumọ, ti ko si sẹni to mu wọn. Nibi ti awọn Boko Haram ti n paaya tọsan-toru! Nibi ti awọn janduku ti n pa ọba alaye! Nibi ti awọn ti wọn n ṣejọba ti n fojoojumọ ko owo ilu jẹ! Nibi ti ijọba apapọ ti n ji owo ati ohun-ini awọn ijọba ipinlẹ ko! Nibi ti awọn ọmọ Naijiria ko ti i jẹun yo, ṣugbọn ti awọn to n ṣẹjọba Naijiria n lọọ fun awọn ara Nijee ni ounjẹ! Nibi ti awọn ọmọ Naijiria ko ti i ri epo bẹntiroolu ra lowo pọọku, ṣugbọn ti ijọba n ko epo wa lọ si Nijee! Nibi ti ọga ọlọpaa patapata ko ti le paṣẹ fawọn ọlọpaa puruntu ki aṣẹ naa mulẹ! Nibi ti awọn ṣoja ti n sa fun awọn janduku afẹmiṣofo! Nibi ti ko ti si araalu kan to mọ ohun to n ṣẹlẹ nile ijọba! Ta waa lo n paṣẹ ni Naijiria! Ta ni olori wa ni Naijiria! Buhari ni abi Ọṣinbajo! Awọn ṣọja ni abi Boko Haram! Ta ni olori wa ni Naijiria kẹ ẹ sọ fun wa o!
Abi wọn lu maanu yii loruka aluwo ni
Ko si ohun ti iba dun to ki wọn lu ọkunrin yii loruka gbigbona, oruka aluwo! Ko waa jẹ bo ṣe yikata, to ṣubu nni, ko jẹ awọn obinrin ni yoo tọ si i lori ti yoo fi dide. AbdulahiRasheed Maina ni o, ọmọ Mọla to ko owo awọn oṣiṣẹ-fẹyinti jẹ. Ko yẹ ki ẹ gbagbe Maina, ileeṣẹ ti wọn ti n sanwo fun awọn oṣiṣẹ ijọba apapọ ti wọn ba fẹyinti lẹnu iṣẹ ọba lo ti n ṣiṣẹ. Ṣugbọn gbogbo owo ifẹyinti awọn ẹni ẹlẹni ti Maina gba, oun ati awọn ti wọn jọ n ṣiṣẹ lo jọ n ko owo naa jẹ. Obinrin kan ninu wọn ti wa lẹwọn bayii lati bii ọdun mẹrin. Njẹ ki Maina si waa doju kọ ijiya ẹsẹ rẹ, niṣe lo bẹrẹ si i sa kiri. Ṣe o ti sa lọ si Amẹrika, nigba to nile nibẹ, ko too tun waa sa pada wa si Dubai, nigba ti ijọba si bọ sọwọ Buhari, o sa pada wa sile. N ni wọn ba bẹrẹ si i ba a ṣẹjọ, igba ti ẹjọ naa si fẹẹ le, ti wọn jaja gba beeli rẹ, niṣe lo sa lọ si ile ẹ to wa ni orilẹ-ede Nijee, o yaa jokoo sibẹ. Ọpẹlọpẹ awọn ọlọpaa agbaye ti wọn ba wọn mu un. Nigba to sọ kalẹ ninu ẹronpileeni lọsẹ to lọ lọhun-un, niṣe lo n rin kebekebe lọ o. Afi bo ṣe di ọjọ keji ti wọn gbe e de ile-ẹjọ, lo ba dẹni to loun ko le rin mọ, lo ba n fi ṣia rin, o loun ti yarọ. Eyi ti a si maa ri ni pe lọjọ keji, niṣe lo ṣubu yakata niwaju adajọ, to ni aisan to n ṣe oun ti le si i. Aisan ti ko ṣe e ni gbogbo igba to wa ni Nijee, ti ko ṣe e lọjọ ti wọn mu un de, ti ko ṣe e ko too de iwaju adajọ, to waa jẹ niwaju adajọ ni aisan naa ki i mọlẹ to fi ṣubu, ta ni ko waa mọ pe irọ ni Maina n pa. Bo ṣe ṣubu wọlọbi lọjọ naa lo fi da bii ẹni ti wọn lu loruka aluwo, ṣugbọn oruka kọ ni wọn lu u, jagunlabi fẹẹ sa lọ ni. Ọmọ akẹ! Ẹ ma jẹ ko lọ o! Bo ba sa lọ bayii, ko ni i pada wa mọ o. Ẹ yaa jẹ ko jiya ẹṣe ẹ. Ẹ jẹ ko ṣẹwọn ẹ! Bo ba fẹẹ ku sibẹ ko tete ku sibẹ! Ẹ ma jẹ ki Maina sa lọ o, owo awọn oṣiṣẹ-fẹyinti wa lọwọ ẹ. Ẹ dakun, ẹ ba wa gba owo wọn lọwọ ẹ. Ko kuku sẹni kan to ko ba Maina, iya ẹṣẹ Maina ni Maina n jẹ.