O ṣoju mi koro (Apa Kin-in-ni)

Adaluru lawọn eeyan bii Daura yii o

Ki i ṣe gbogbo eeyan lo mọ Maman Daura, baba kan to sun mọ Buhari ju ẹnikẹni lọ ni Naijiria loni-in yii ni. Ko gba iṣẹ ijọba o, ki i ṣe minisita, ki i ṣe gomina, ki i ṣe oluldamọran, sibẹ, inu Aso Rock lo n gbe pẹlu Buhari. Wahala baba naa pọ debii pe ija rẹpẹtẹ ni iyawo Buhari ati oun Daura n fi ọpọ ọjọ ja, ija naa si ti de ori awọn ọmọ wọn. Daura yii ni olori awọn mẹta ti wọn n dari Buhari lati igba to ti n ṣejọba rẹ. Awọn meji to ku, Abba Kyari ati Ismail Issa Funtua, ti ku bayii o, o waa ku oun nikan ati eti rẹ, ṣugbọn pẹlu pe oun nikan lo ku yii naa, o ṣi n fẹẹ maa dari Buhari, bẹẹ lo fẹ ki awọn Fulani ẹlẹgbẹ wọn mọ pe oun ni aṣoju wọn. Baba yii sọrọ kan lọsẹ to kọja, ọrọ naa si ti di ariwo rẹpẹtẹ. O ni ki Naijiria yee lo eto pe bi awọn Hausa-Fulani Ariwa ba jẹ Aarẹ tan, ki awọn ara Guusu (Ibo tabi Yoruba) naa tun jẹ. O ni bo ba jẹ ọmọ Hausa lo kun oju oṣuwọn ju, to mọwe, to si ni iriri ju, oun ni ki wọn jẹ ko ṣejọba, bo ba si jẹ Ibo tabi Yoruba ni, oun naa ni ki wọn yan sile ijọba.Pe ẹni to ba mọ eto ijọba ni ka gbe e fun, ki a ma fi ẹlẹyamẹya ṣejọba Naijiria mọ. Ọrọ naa dara daadaa, o si dun leti, bo si ṣe yẹ ki o ri gan-an niyẹn. Ṣugbọn alaboosi lawọn eeyan bii Daura yii, wọn kan fẹẹ da nnkan ru ni, nitori ẹ ni ko ṣe si ẹni to gba ọrọ naa gbọ, ti wọn si bẹrẹ si i pariwo pe ki baba arugbo yii gbẹnu sọhun-un jare. To ba jẹ bi awọn Hausa-Fulani ti n ṣe lati ọjọ yii wa niyi ni, to ba jẹ ọrọ ti Daura sọ yii, o ti n sọ iru rẹ lọjọ to ti pẹ, ati nigba ti Buhari ti gbajọba yii, gbogbo ohun buruku to n ṣẹlẹ ninu ijọba yii ko ni i ṣẹlẹ, ohun gbogbo iba si dara fun Naijiria ju bayii lọ. Ẹgbọn ati ọrẹ timọ timọ Buhari ni Daura yii, ṣugbọn awọn ni wọn n gba Buhari nimọran debii pe ti wọn ba yọ ọmọ Yoruba tabi Ibo to ni iriri, to mọwe, to si ti pẹ lẹnu iṣẹ ijọba kan kuro nipo giga, puruntu ọmọ Mọla ti ko mọ kinni kan, apa amuṣua, ati eeyan ti ko si iwa ọmọluabi kan lara ẹ ni wọn yoo lọọ fi rọpo eeyan gidi ti wọn yọ kuro nipo kan, ko si si ohun ti wọn yoo ṣe gbe e lọ sibẹ ju pe o jẹ ọmọ Hausa-Fulani lọ. Ṣebi awọn Daura yii ni wọn wa nidii iwa raurau bẹẹ. Ki lo de ti Daura ko sọ nigba ti Yoruba tabi Ibo n ṣejọba pe ki wọn ma fi ọrọ ẹlẹyamẹya ṣe e, ṣebi oun naa wa ninu awọn ti wọn maa n pariwo pe Hausa lo kan, ilẹ Hausa ni wọn gbọdọ gbe ipo Aarẹ wa, awọn Yoruba ati Ibo ti ṣe tiwọn. Bo ba ṣe pe ni asiko awọn Yoruba tabi Ibo ni Daura jade, to ni ki wọn mu ọlọgbọn ati ẹni to ni iriri jade waa ṣejọba, ki wọn ma mu eeyan nitori pe o jẹ ọmọ Hausa, gbogbo aye ni yoo kin in lẹyin, ti wọn yoo si mu eeyan gidi kan jade. Ṣugbọn Hausa wo ni wọn gbe si ile iṣẹ ijọba Naijiria ti ki i ṣe pe o ba ibẹ jẹ ni. Wọn yoo ba ibẹ jẹ, tabi ki wọn jẹ ileeṣẹ naa pa. Ṣebi oun Daura yii naa ṣe olori ileeṣẹ ijọba ri, ki lo ṣẹlẹ si ileeṣẹ ti wọn fi i ṣe olori ẹ, ṣebi o parẹ naa ni. Ki lo de ti wọn n rọ awọn ọmọ Hausa-Fulani wọ inu iṣẹ ologun, wọn mọwe, wọn o mọwe, ki lo de ti o jẹ ọmọ Hausa-Fulani ni wọn n ko si ileeṣẹ ijọba gbogbo, nigba ti gbogbo aye mọ pe wọn ko ni iriri, bẹẹ ni wọn ko kawe debi ti wọn yoo fi le di iru awọn ipo bayii mu. O daa ti ijọba Buhari tete jade pe ọrọ ẹnu Daura funra ẹ lo n sọ, ki i ṣe ọrọ ijọba, nitori ko si ẹni ti yoo gba fun wọn o. Ni 2023, Guusu ilẹ Naijiria lo kan lati mu Aarẹ wa, boya lati ilẹ Yoruba ni o, tabi lati ilẹ Ibo. Ṣugbọn pe boya Hausa ni yoo tun ṣejọba Naijiria lẹyin Buhari, tawọn adaluru bii Daura yoo sọ pe o ni iriri, o si mọwe, iyẹn ko ni i ṣee ṣe, afi ka kuku da gbogbo ẹ ru lẹẹkan.

 

Asasi awọn Boko Haram ti mu Buhari atawọn eeyan ẹ

Dajudaju, asasi awọn Boko Haram yii ti mu Buhari, o si mu awọn eeyan rẹ ti wọn jọ n ṣejọba. Bi ko ba ṣe bẹẹ ni, awọn eto to n jade lati ọdọ wọn yii lori ọrọ awọn Boko Haram ko ni i jade rara. Ijọba Buhari ko awọn Boko Haram jade, wọn ni wọn ti yipada, wọn lawọn ko paayan mọ, wọn kọ wọn niṣẹ baaba, wọn fun wọn ni ogun ẹgbẹrun pe ki wọn maa fi ṣe aye wọn. Ṣugbọn ọlọgbọn eeyan yoo mọ pe eleyii ko ṣee ṣe, nitori ko ni i mu oore kankan wa fun ilu. Awọn ọlọgbọn, onilaakaye, si sọ fun ijọba yii to o, ṣugbọn wọn ko gba, awọn ni oun to dara ju loju awọn niyẹn. Awọn ti awọn Boko Haram pa iya wọn, ti wọn pa baba wọn, ti wọn sọ di alaabọ ara, ti wọn le ni ibugbe wọn, ti wọn di isansa ati alarinkiri, awọn yẹn wa nibẹ o, ijọba Buhari ko ya si wọn. Kaka bẹẹ, awọn apaayan yii gan-an ni ijọba yii waa mu, ti wọn sọ di ọmọ tuntun, ti wọn si n gbe wọn gẹgẹ, ti wọn ni wọn ti yiwa pada. Gbogbo bawọn eeyan ti n sọ pe iru awọn afẹmiṣofo bayii ki i yipada bọrọ, bii ase lasan lo n jọ loju wọn. Oun naa lo ti n ṣẹlẹ yii o. Aṣofin Ndume lati ipinlẹ Borno ni ninu awọn ọmọ ti wọn lo ti yipada yii lọọ ka baba ẹ mọle, o si ṣa a pa, o si ko gbogbo maaluu ẹ sa lọ, bẹẹ lo wọ inu igbo tẹnikan ko ri i mọ. O ni ọpọlọpọ awọn ọmọ naa ni wọn n ṣe aṣemaṣe oriṣiiriṣii, ti wọn si n sa pada sinu igbo lẹsẹkẹsẹ, ibi ti wọn n sa lọ ko ye ẹnikan. Nibo ni wọn tun fẹẹ sa lọ ju inu igbo lọdọ awọn ẹlẹgbẹ wọn ti wọn jẹ Boko Haram yii lọ, tabi ki wọn lọọ da ẹgbẹ janduku, ẹgbẹ ajinigbe tiwọn silẹ, ki wọn si bẹrẹ si i da ilu laamu kaakiri. Ni gbogbo aye loni-in, bi wọn ba mu awọn afẹmiṣofo yii nibi kan, kia ni wọn n pa wọn, tabi ki wọn ko wọn kuro niluu, ti wọn yoo si mọ pe awọn apaayan yii n dinku diẹ diẹ lawujọ wọn. Ṣugbọn ni Naijiria, bi ijọba tiwa ba ti mu awọn Boko Haram, wọn yoo bẹrẹ si i ṣe wọn bii ọmọ tuntun ti wọn bi, wọn yoo maa ra miliiki fun wọn, wọn yoo maa fun wọn lounjẹ ti awọn ti wọn ko paayan ri ko ri jẹ, awọn yẹn ni yoo si jẹun wọn yo titi ti wọn yoo fi ju wọn silẹ pe wọn ti yipada, wọn yoo si pada saarin awọn eeyan wọn ninu igbo. Iru ijọba wo leleyii bayii Olodumare! Tabi loootọ lasasi awọn Boko Haram ti mu wọn ni!

 

Ẹ wo bi wọn ṣe fẹẹ pa odidi gomina kan danu

Bi ko ba jẹ pe Ọlọrun wa lẹyin Gomina Zulum, ti ipinlẹ Borno, wọn iba pa a danu lọsẹ to kọja yii. Awọn Boko Haram ni, wọn iba ti yanju rẹ lẹẹkan. Awọn eeyan royin pe ninu awọn gomina to ti n jẹ nipinlẹ Borno, ọga lọkunrin yii, pe loootọ loootọ lo mura lati mu idagbasoke ba awọn eeeyan rẹ. Ṣe ipinlẹ yii, Borno, ni ogun Boko Haram pọ si ju lọ. Titi di bi a ṣe n wi yii ni wọn ṣi n gbe awọn eeyan, ti wọn si n pa awọn mi-in, awọn abule mi-in si ti wa to jẹ Boko Haram yii lo n paṣẹ ibẹ, wọn ti gba ibẹ lọwọ ijọba Naijiria patapata. Meloo meloo lawọn eeyan ti wọn ti le nile wọn, ati awọn ti wọn ti gba gbogbo ohun-ini wọn. Lati mu nnkan bọ sipo, Gomina Zulum ni oun yoo da awọn yẹn pada si aaye wọn, oun yoo si mọ bi oun yoo ṣe pese iṣẹ ti awọn ti Boko Haram yii ti pa saye yoo ṣe bẹrẹ igbe-aye tuntun. Nidii eyi, gbogbo ibi ti wọn ba ti ko awọn eeyan pamọ si, awọn abule ti wọn ti le wọn nibẹ tẹlẹ tawọn yẹn tun ṣẹṣẹ n pada si, gbogbo ibi ti ọkunrin gomina yii n ṣe abẹwo si niyẹn. Bo ba ti debẹ, yoo ba wọn sọrọ pe ohun gbogbo yoo daa laipẹ, yoo si fun wọn ni ounjẹ ati owo ti wọn yoo maa na, pẹlu awọn nnkan mi-in ti wọn nilo gidi. Ọsẹ to waa kọja yii lo lọ si Baga, ibi ti wọn ti mọ tẹlẹ pe awọn Boko Haram lo gbajọba ibẹ. Ṣugbọn ki i deede lọ, awọn ọga ṣọja ti wọn ti ko sibẹ lati ọjọ yii wa ni wọn fọkan ẹ balẹ pe nibi yoowu ni ipinlẹ Borno, ko si awọn Boko Haram ẹyọ kan bayii mọ. N loun ba gbera, o ku dẹdẹ ki wọn wọ Baga ni wọn da ina ibọn bo o, bi ko si jẹ pe o rakoro kuro nibẹ ni, ibẹ ni wọn iba pa a si. Inu bi gomina naa, o fibinu sọrọ sawọn ṣọja. Ṣugbọn ṣe awọn ṣọja yii ni yoo ba wi ni abi ijọba Buhari, abi Buhari to ko awọn olori ologun sibẹ lati ọjọ yii ti wọn ko ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ, ti ko si le wọn kuro, bẹẹ lo si mọ pe apa wọn ko ka iṣẹ ti wọn gbe fun wọn ṣe. Afi bii epe nijọba yii, Ọlọrun nikan lo mọ ohun tawọn ọmọ Naijiria ṣe to fi ran iru ẹ si wọn.

 

Awọn alaraka, aṣe olowo ki i fẹẹ ku

Oniranu kan ṣaa lawọn Ijẹbu n pe ni alaraka, iru wọn lawọn eeyan ti a si ko kun ile ijọba wa. Nitori ẹ ni wọn ṣe fẹẹ yagbẹ sara, wọn fẹẹ daku lọsẹ to kọja yii, koda, eeyan ko ro pe iru ariwo bẹẹ le ti ẹnu wọn jade. Ọkunrin kan lo ko wahala yii si wọn lagbada o, ni wọn ba bẹrẹ si i sare kiri, ti wọn n fooro ẹmi ara wọn. Chidi Chukuanyi, olori ẹgbe oṣelu ADP, lo sọ pe asiko ti to ni Naijiria ki wọn lo iru eto ti Jerry Rawlings lo fun gbogbo awọn oloṣelu ilẹ Ghana lọdọ wa ni Naijiria naa. N lawọn Buhari ati awọn eeyan rẹ ba fẹẹ fori sọlẹ, ibi ti ọrọ naa gba lara wọn ko dara rara. Olori ijọba ilẹ Ghana ni Rawlings nigba kan. Ijọba ologun lo ṣe. Asiko ti wahala ati ikowojẹ awọn oloṣelu to jẹ olori ijọba alagbada ilẹ naa pọ ju lo gbajọba, n lo ba wadii gbogbo awọn oloṣelu naa awọn to si kowo jẹ ninu wọn, wọn yinbọn pa wọn ni gbangba ode ni. Iru ẹ ni Chidi ni ko ṣẹlẹ ni Naijiria nitori ikowojẹ buruku to n lọ laarin awọn ọmọ ẹyin Buhari wọnyi nile ijọba. Bi awọn ọmọ Buhari ṣe gbọ ọrọ naa ni wọn wọ ṣokoto ija, Lai Muhammed sare jade, o ni ko si ijọba kan to n gbogun ti iwa ibajẹ ju ijọba Buhari yii lọ. Lo ṣaa lọgun titi, lo fi ọwọ luwọ, lo fi ete lu ete, ṣugbọn nigba ti pupọ ninu awọn eeyan mọ pe irọ a maa pọ ninu ọrọ ọkunrin naa ju, wọn ko ka ọrọ rẹ si nnkan gidi kan. Afi bi awọn olori ologun ilẹ wa ṣe sare jade, ti wọn bẹrẹ si i ke ewi gidi. Wọn ni ṣọja kan ko gbọdọ gbajọba, gbogbo ṣọja gbọdọ mọ pe ka fi ibọn gbajọba lodi sofin, wọn ko gbọdọ dan an wo, wọn gbọdọ duro lẹyin ijọba Buhari yii ni. Wọn ṣaa n pariwo oriṣiiriṣii bẹẹ, nitori ọrọ ti ọkunrin yii sọ. Aṣe bayii ni wọn bẹru iku to, ti wọn si n fi iku pa awọn araalu. Aṣe bayii ni wọn bẹru iya to, ti wọn n fiya jẹ gbogbo wa. Bi iwọ ba ṣe rere, ara ki o ha ya ọ. Bi ijọba Buhari ba mọ pe awọn ṣe daadaa to fawọn araalu, kin ni wọn n bẹru bi ṣọja yoo gbajọba tabi ko ni i gbajọba si. Iyẹn ni pe awọn naa mọ pe ohun tawọn n ṣe yii ko dara. Eeyan kọ ni yoo da ẹjọ eleyii o, Ọlọrun funra rẹ ni yoo da a. Ẹ maa rẹ wa jẹ niṣo, Ọlọrun n bọ ti yoo fi iya to tọ jẹ gbogbo ẹyin ọjẹlu ati ẹyin oloṣelu oniṣẹ ibi.

Leave a Reply