Monisọla Saka
Adajọ agba pata nilẹ wa, Olukayọde Ariwoọla, ti i ṣe adajọ agba ilẹ Naijiria (CJN), ti pọn sẹyin ọmọ iya rẹ, Gomina Ṣeyi Makinde ti ipinlẹ Ọyọ, o ni o dun mọ oun bo ṣe wa lara awọn gomina marun-un ẹgbẹ PDP. Awọn gomina marun-un ọhun ti wọn n binu si ẹgbẹ oṣelu wọn yii naa ni wọn tun n pe ni ‘gomina ọmọluabi’.
Ariwoọla sọrọ yii nibi ayẹyẹ ti Gomina Wike, ṣe fun un ni gbọngan igbalejo wọn niluu Port Harcourt, olu ilu ipinlẹ Rivers, lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kọkanla, ọdun yii.
Ariwoọla to jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Ọyọ loun naa ni alejo pataki ti Wike ranṣẹ pe lati ba a ṣi awọn iṣẹ akanṣe kan ti ijọba rẹ ṣẹṣẹ pari lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ta a wa yii.
Awada ni Ariwoọla kọkọ ba olugbalejo ẹ, Wike ṣe, nigba to sọ pe ko ma ṣe halẹ lati gba iyawo Makinde to wa lati ipinlẹ Rivers lọwọ awọn. O waa fi kun un pe Makinde yoo mu Wike bii awokọṣe nibi iṣẹ daadaa to n ṣe nipinlẹ naa.
O ni, “Ara idi ta o ṣe gbọdọ foya lati ni awọn eeyan ọmọluabi yii layiika wa niyi. Bẹẹ ni inu mi dun gidi gan-an pẹlu bi gomina mi naa ṣe wa lara wọn, nitori yoo ri awọn ẹkọ kan mulo lara ọrẹ ẹ to tun jẹ ana fun un, tori gbogbo wa la wa sibi lati waa tọrọ iyawo fun gomina wa lọjọ naa lọhun-un.
Gomina Wike a waa maa tori ẹ dunkooko mọ wa pe oun maa gba aburo oun pada ti gomina ipinlẹ mi o ba ṣe daadaa. Nitori ẹ lẹ ṣe maa n ri i ti yoo maa gbọn tẹlẹ e lẹyin, nitori ko fẹ ki wọn gba iyawo oun pada”.
O waa lu gomina Rivers naa lọgọ ẹnu fun ẹkọ rere to ṣee mu lo to fi lelẹ nipinlẹ Rivers, ati pe lọpọ igba ni Wike ti sọ pe oun ko ni i yee ṣiṣẹ akanṣe lọlọkan-o-jọkan, titi ti saa eto ijọba oun fi maa pari.
Bakan naa lo tun gboṣuba kare fun gomina ọhun fun atilẹyin ẹ sileeṣẹ eto idajọ nigba gbogbo, latigba to ti dori ipo lọdun 2015.
O tun tẹsiwaju pe, “Yoo nira ka a to le ri ẹni to maa ṣe kọja awọn iṣẹ daadaa ti Wike ti ṣe silẹ de awọn arọmọdọmọ wọn yii. Nitori bẹẹ lo si ṣe maa n tẹnu mọ ọn pe, loootọ loun o ni i ku si ipo gomina, ṣugbọn gbogbo ọjọ yoowu toun ba lo nipo, oun yoo ri i daju pe o so eeso rere.
Gbogbo awọn nnkan to si ti n ṣe lati ọjọ yii wa fi ye wa pe ko si ohun to n di awa eeyan lọwọ lati ṣe ohunkohun, bẹẹ ni a le ṣe daadaa ju ba a ṣe lero lọ”.
Ninu ọrọ tiẹ, Gomina Wike gba a laduura fun adajọ agba pe Ọlọrun yoo tọ ọ sọna niru akoko to lagbara yii.
Tẹ o ba gbagbe, awọn gomina marun-un ọhun, Nyesom Wike, ti i ṣe Gomina ipinlẹ Rivers, to si tun jẹ aṣaaju awọn gomina marun-un ọhun, Gomina ipinlẹ Benue, Samuel Ortom, to jẹ alaga wọn, Gomina Okezie Ikpeazu, tipinlẹ Abia, Ṣeyi Makinde ti ipinlẹ Ọyọ ati Gomina ipinlẹ Enugu, Ifeanyi Ugwuanyi ni wọn ni awọn ko ni i ṣatilẹyin fun oludije funpo aarẹ lẹgbẹ wọn, Atiku Abubakar, afi to ba yọ Alaga wọn, Iyorchia Ayu, nipo.