O ga o! Wọn fẹẹ fi ida ṣa Peter Obi pa lasiko ipolongo ẹ n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ori lo ko oludije fun ipo aarẹ orileede yii labẹ ẹgbẹ oṣelu Labour Party (LP), Ọmọwe Peter Obi, yọ lọwọ ikọlu to ṣee ṣe ko gbẹmi ẹ  n’Ibadan l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kọkanla yii, pẹlu bi ọwọ ṣe tẹ afurasi agbanipa ọhun nibi to ti n wa ọna lati gun ọkunrin to n dupo aarẹ naa pa.

Nibi ipolongo ibo aarẹ ẹgbẹ oṣelu Lebọ, eyi to waye ni papa iṣere Lekan Salami l’Adamasingba, n’Ibadan, niṣẹlẹ ohun ti waye nirọlẹ Ọjọruu, nigba ti ọkunrin afurasi apaayan naa duro soju ọna ti oludije fun ipo aarẹ lorukọ ẹgbẹ oṣelu naa ni lati gba kọja pẹlu erongba lati fi nnkan ija ọwọ ẹ ṣe e nijanba nibi ti ọpọ eeyan ba ti n rọ girigiri lati ki i nigba to ba de si papa iṣere naa.

Ọlọpaa inu ni gbogbo eeyan kọkọ pe e nitori kootu dudu kirikiri bii tawọn DSS lo wọ, laimọ pe jagunlabi ti fi ida to mu yanranyanran kan pamọ sabẹ kootu naa, nnkan ija oloro to fi pamọ sabẹ aṣọ yii lo si tu u laṣiiri ti awọn agbofinro fi mu un.

A gbọ pe ninu ọrọ ti wọn fi wa ọkunrin alaṣọ dudu naa lẹnu wo laṣiiri ti tu pe alakọri ki i ṣe oṣiṣẹ eleto aabo rara.

Akitiyan ALAROYE lati mọ orukọ afurasi ọdaran yii ko seso rere pẹlu bi akitiyan akọroyin wa lati ba SP Adewale Ọṣifẹṣọ ti i ṣe Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ sọrọ ko ṣe ti i seso rere titi ta a fi pari akojọ iroyin yii.

Pẹlu iṣẹlẹ yii, a gbọ pe awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu Lebọ ti fun okun eto aabo le daindain si i lati daabo bo oludije dupo aarẹ wọn.

Gẹgẹ bi igbimọ kan to n polongo ibo fun Peter Obi ṣe kọ ọ sori ikanni ayelujara wọn pẹlu fọto afurasi ọdaran naa, wọn ni “ọwọ ba ọkunrin yii nibi to ti duro tifuratifura pẹlu ida oloju meji loju ọna ti Peter Obi maa gba kọja nibi ipolongo ibo ta a ṣe ni ipinlẹ Ọyọ lọjọ Wẹsidee.

“Lati asiko yii lọ, eto abo to lagbara la o maa pese fun Peter Obi ati ni ayika ibi gbogbo to ba wa”.

Leave a Reply