Taofeek Surdiq, Ado-EkitiNṣe ni jinijini ati ibẹru gba gbogbo ọkan awọn eeyan ilu Ado-Ekiti lọjọ lṣẹgun, Tuside, ni pataki ju lọ awọn to n gbe ni agbegbe Dalemo, laduugbo Adehun, niluu Ado-Ekiti.
Obinrin alaaganna kan lo ṣa ọmọ ọdun maje kan, Demilade Fadare, pa.Iṣẹlẹ to da ibẹru silẹ ni gbogbo adugbo naa waye laaarọ ọjọ lṣẹgun, Tuside, ọsẹ yii.Gẹgẹ bi awọn araadugbo naa ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju rẹ ṣe sọ, wọn ni iya ọmọ obinrin yii lo ran an niṣẹ ni aago mẹjọ aabọ alẹ ọjọ Aje, Mọnde, lọ si ile kẹta, nibi ti obinrin were naa n gbe.Ṣugbọn lẹyin wakati diẹ ti iya ọmọ naa ko ri i ko pada sile lo kigbe sita ti gbogbo awọn araadugbo si darapọ mọ iya ọmọde naa lati wa a.Lẹyin wakati die ni wọn lọọ fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa atawọn ajọ sifu difẹnsi leti.
Awọn naa tun darapọ mọ awọn araadugbo naa lati ṣe awari ọmọdebinrin yii.Ṣugbọn ni kutukutu aarọ ọjọ Aje, Mọnde, ni okiki kan pe wọn ti ri oku ọmọdebinrin naa ni ile kẹta to jẹ ile oluṣọaguntan ijọ Irapada (Redeem. Church)Ṣugbọn ohun to jẹ iyalẹnu níbẹ ni pe obinrin were yii ti pa ọmọdebinrin yii, o ti ṣa a si wẹwẹ o si ko oku ẹ sinu abọ nla kan ninu ile naa.Wọn ni were yii ti sa kuro ninu ile ni kete ti ìṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.Eyi lo bi awọn ọdọ adugbo naa ninu ti wọn fi fina sinu ile naa. Bakan naa ni wọn tun ba dukia olowo iyebiye miiran jẹ ninu ile naa.
Nigba to n sọrọ lori ọrọ naa, Alukoro ajọ ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, sọ pe ọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ were naa.O ṣalaye pe awọn ọlọ́pàá ti gbe oku ọmọdebinrin naa lọ sí ile igbokuu-pamọ si. Bakan naa ni kọmiṣanna ọlọpaa ti paṣẹ pe ki awọn ọlọpaa bẹrẹ iwadi lori ọrọ naa.