O ma ṣe o,  awọn janduku pa eeyan mẹtala ninu mọlẹbi kan naa ni Kogi

 Eeyan mẹrinla lawọn janduku kan pa loru Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, nipinlẹ Kogi, nigba ti awọn bii mẹfa fara pa yanna yanna.

 Ninu awọn mẹrinla to pade iku ojiji yii, mẹtala ninu wọn lo jẹ ọmọ mọlẹbi kan naa. Ẹyọ ẹni kan ṣoṣo lo si ku ninu wọn to jajabọ lọwọ iku oro naa.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Kogi, Ede Ayuba, lo ṣalaye ọrọ naa fawọn oniroyin niluu Lọkọja, lọsan Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

Ọga ọlọpaa naa ni ni nnkan bii aago meji oru ni oun gba ipe ọkan ninu awọn ọmọọṣẹ oun pe awọn janduku kan ti ya wọ Abule Agbudu yii, nijọba ibilẹ Konton-Karfe, ti wọn si n ṣọṣẹ buruku nibẹ.

O ni oju ẹsẹ loun ti pe awọn agbofinro to wa ni agbegbe naa lati pe awọn fijilante atawọn ọlọpaa pe ki wọn ṣigun lọ si ibi iṣẹlẹ naa lati doola ẹmi awọn eeyan abule ọhun.

Ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe awọn ẹni ibi naa ti ṣiṣẹ ọwọ wọn ki wọn too debẹ, wọn si ti sa lọ. Eeyan mẹrinla ni wọn ti pa, ti awọn mẹfa si fara pa yanna yanna.

ALAROYE gbọ pe ninu awọn mẹrinla to ku naa, mẹtala ni wọn jẹ mọlẹbi kan naa, ti wọn jọ n gbe papọ. Ẹni kan ṣoṣo lo si mori bọ ninu ile naa ti wọn ko pa.

Leave a Reply