O ma ṣe o, awọn meji ku nibi ti wọn ti n ṣewọde SARS l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Iwọde SARS to n lọ lọwọ kaakiri awọn ilu nipinlẹ Ondo gbọna mi-in yọ l’Ọjọbọ, Tosidee, ọsẹ ta a wa yii, pẹlu bi meji ninu awọn olufẹhonu han ọhun ṣe ku sinu ijamba ọkọ to waye niwaju ile ijọba to wa  l’Alagbaka, niluu Akurẹ.

AKEDE AGBAYE gbọ pe ọkọ Toyota Camry kan ti nọmba rẹ jẹ LND 778 GL to sọ ijanu rẹ nu lo ṣeesi kọlu awọn mejeeji ọhun lori ọkada ti wọn wa, ti wọn si ṣe bẹe ku loju ẹsẹ.

Akurẹ ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Ondo ati ilu Ondo, ni wọn kọkọ berẹ ifẹhonu han yii l’Ọjọruu, Wẹsidee.

Aarọ kutukutu Ọjọbọ, Tọsidee, lawọn to n ṣe iwọde naa tun ti ko ara wọn jọ si agbegbe Adegbenle, niwaju ileesẹ to n ri sọrọ aṣa ati iṣe l’Akurẹ, lati bẹrẹ ifẹhonu mi-in lakọtun.

Oju ọna Fiwaṣaye si Ọja-ọba ti wọn di pa lasiko iwọde naa lo ṣokunfa bi awọn onimọto ati ọlọkada ṣe wa ọna mi-in gba, ọna onibeji to gba iwaju ile ijọba kọja si wa lara awọn ọna tawọn ọlọkọ wọnyi n gba ki wọn le raaye de ibi ti wọn n lọ lasiko.

Wọn ni loju ẹsẹ ni wọn ti gbe oku awọn mejeeji lọ si mọsuari ileewosan ijọba to wa l’Akurẹ, nibi ti wọn wa ni gbogbo asiko ta a fi n kọ iroyin yii lọwọ.

Leave a Reply