O ma ṣe o, gbajumọ oṣere tiata binu gbe majele jẹ

Faith Adebọla

Inu ibanujẹ ati idaro lawọn mọlẹbi, ọrẹ ati alajọṣe irawọ oṣere tiata ilẹ wa kan, Esther Nwachukwu, wa lasiko yii, pẹlu iku ojiji ti ọmọbinrin arẹwa naa ku, bẹẹ ni wọn n ṣe kayeefi lori iku to pa a, tori niṣe ni wọn lo para ẹ, majele lo gbe jẹ.

Iṣẹlẹ ibanujẹ to waye lopin ọsẹ to lọ yii, bẹrẹ si i ja ranyin lori ẹrọ ayelujara, nigba ti mọlẹbi oloogbe naa, Ifeoma Nwachukwu, fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ pe loootọ ni aunti oun ti jade laye.

Tori bọrọ naa ṣe ba wọn lojiji, awọn ololufẹ oloogbe naa kọkọ ro pe ẹfẹ buruku ni Ifeoma n ṣe, afi bi ọrọ ti wọn pe ni ṣereṣere naa ṣe ja si ootọ, wọn ni majele lo pa a.

Bo tilẹ jẹ pe inu fiimu elede Gẹẹsi ni onitiata yii ti kopa, o jẹ oṣere to jafafa lagbo awọn oṣere. Awọn eeyan si maa n gbadun rẹ ninu fiimu to ti ṣere.

Lawọn igba kan, awuyewuye dide nipa oṣere yii, nigba to lọọ ya aworan oṣere-kunrin onitiata ẹgbẹ ẹ tawọn eeyan mọ si Junior Pope sara ẹ, eyi si bi iyawo ọkunrin naa, Jeniffer Awele, ninu.

Ṣa, iwadii ti n lọ lori ohun to ṣokunfa bi oloogbe yii ṣe gbẹmi ara ẹ.

Leave a Reply