O ma ṣe o, gende-kunrin ko sodo n’llọrin, oku ẹ ni wọn gbe jade

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Gende-kunrin ẹni ọdun mejilelogun kan torukọ rẹ n jẹ Sodiq Mustapha, ọmọ agboole Sheji, Kankatu,  lagbegbe Okelele, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, ti dagbere faye bayii, lẹyin to ko si odo Agba Daamu, eyi to wa niluu Ilọrin.

Agbẹnusọ ajọ panapana nipinlẹ Kwara, Hassan Hakeem Adekunle, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ sọ pe ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, ni ajọ naa ri oku gende-kunrin ọhun gbe jade ninu omi Daamu ọhun, ni nnkan bii, aago mẹwaa owurọ ku beleja lẹyin ti iroyin kan ileeṣẹ panapana pe ọmọkunrin naa ti ko sodo. O tẹsiwaju pe niṣoju kọmiṣanna to n ri si ọrọ omi nipinlẹ Kwara, ati akowe agba ileeṣẹ to n ri si ọrọ omi ni awọn ti yọ oku ọmọ kunrin ọhun kuro  ninu odo.

Adari agba ajọ panapana ni Kwara, Ọmọọba Falade John Olumuyiwa, ti wa kẹdun pẹlu mọlẹbi oloogbe, bakan naa lo gba awọn obi nimọran lati maa kiyesi irin awọn ọmọ, ki wọn mọ ibi ti wọn o maa rin si lati le pinwọ bi awọn ọmọde ṣe maa n ba omi lọ.

Leave a Reply