O ma ṣe o, Oriṣabunmi ti ku

Jide Alabi

Ajalu nla ti tun ja lu awọn oṣere ilẹ wa pẹlu bi ọkan pataki ninu wọn Fọlakẹ Arẹmu, ti gbogbo eeyan mọ si Oriṣabunmi ṣe ku lojiji.

Lojiji ni ariwo deede gba ilu kan pe obinrin to ti figba kan jẹ iyawo Oloye Jimoh Aliu toun naa ti ku bayii dagbere faye. Obinrin naa wa nibi eto isinku Jimoh Ali, ko si si ifarahan aisan kankan lara rẹ.

Ko ṣeni to ti i le sọ iru iku to pa obinrin naa. ALAROYE yoo mu ẹkunrẹrẹ iroyin naa wa laipẹ.

Leave a Reply