O ma ṣe o: Sanusi pade iku ojiji

Aderounmu Kazeem

Sanusi Mọrufu, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, kan lo pade iku ojiji lana-an Sannde, ọjọ Aiku, nigba ti ijanba mọtọ ṣẹlẹ laarin ọkọ tanka agbepo ati afẹfẹ idana meji ni Fadeyi, Eko.

Tirela agbepo kan ti wọn kọ Quantum Oil si lara, ti nọmba to wa lara ẹ jẹ, KTU 344 XY ati tanka to gbe gaasi (afẹfẹ idana) ti nọmba tiẹ jẹ JJJ 258 XW ni wọn jọ nijanba ọhun. Laarin awọn tirela meji yii ni Mọrufu ha si, nibẹ gan-an lo ti pade iku ojiji to pa a lọjọ Sannde, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu yii ni bọsitọọbu Fadeyi, niluu Eko.

Ileeṣẹ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri ti sọ pe awọn ti gbe oku ọkunrin to ba iṣẹlẹ ọhun lọ fun awọn mọlẹbi ẹ, ati pe gbogbo wọlu-kọlu ọkọ tijanba ọhun le da silẹ nigboro lawọn ti yanju ẹ bayii.

 

Leave a Reply