O ma ṣe o, baba, iya atawọn ọmọ mẹta ku sinu ijamba ọkọ l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọkunrin awakọ taksi kan, iyawo rẹ atawọn ọmọ wọn mẹta ni wọn ku sinu ijamba ọkọ to waye laarin igboro Akurẹ lalẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, awakọ ọhun lo ṣeesi kọ lu katakata nla kan ti wọn paaki sẹgbẹẹ oju ọna ti wọn n ṣe lọwọ ni Oluwatuyi, lasiko toun atawọn ẹbi rẹ n lọ sile wọn to wa lagbegbe Ijọ Mimọ, ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ ọjọ naa.

Ninu alaye ti ẹnikan to jẹ ẹlẹgbẹ awakọ to ku ọhun ṣe fun wa, o ni ohun to ya awọn lẹnu ni bi ọrẹ awọn ko ṣe ri katakata naa nibi ti wọn paaki rẹ si pẹlu bo ṣe tobi.

O ni ohun ti oun ṣakiyesi ni pe, o ṣee ṣe ki oloogbe ọhun ti muti yo lati ibi ti wọn ti n bọ, leyii to ṣokunfa ere asapajude to n sa titi to fi lọọ wa ara rẹ, iyawo atawọn ọmọ rẹ pa si abẹ katapila.

Ọkunrin to ni ka forukọ bo oun laṣiiri ọhun ni awọn n gbọ oorun ọti to n run jade lati ara rẹ nigba tawọn lọọ wo oku rẹ ni kete lẹyin iṣẹlẹ naa.

Oku awakọ naa atawọn mẹrin yooku lo si wa ni mọsuari ile-iwosan ijọba to wa l’Akurẹ lasiko ta a n kọ iroyin yii lọwọ.

Leave a Reply