Ọkunrin oniṣọọbu puulu (pool) kan, nibi tawọn eeyan ti n ta tẹtẹ ati baba-ijẹbu ninu ọja Kayọde, ni Abule Ijẹṣa nitosi Saabo, lEkoo ti binu para ẹ lanaa o. “Baba Puulu” ni gbogbo eeyan n pe e lọja naa, ko si sẹni to ro pe yoo ku lojiji bẹẹ, agaga ko tun jẹ oun lo para ẹ. Ohun to jẹ ko pa ara ẹ yii ni pe awọn eeyan kan ta tẹtẹ lọdọ ẹ wọn si jẹ, ni ko ba rowo ti yoo fun wọn. N lo ba kuku binu para ẹ.
Ọkunrin naa kọwe silẹ ko too ku. O kọ ọ sinu iwe naa pe Bonny ati Osuma lo pa oun o, ẹni to ba si paayan, pipa ni ki wọn pa a. Lẹyin to ti kọwe yii, to si lẹ ẹ si bii ibi meji mẹta. lo ṣẹṣẹ lọọ para ẹ loru. Igba ti ilẹ ana mọ lawọn ara inu ọja too ri i. Babalọja nibẹ, Najeemdeen Ajadi, ni oun n ṣe kolẹkodọti lọwọ ni wọn waa sọrọ naa foun. Bẹẹ ni Iyalọja, Aderẹmi Thomas, sọ pe bii aago mẹjọ aarọ ni wọn pe oun pe ki oun maa sare bọ lọja, pe Baba Puulu ti pokunso o.
Alaye ti wọn ṣe nigba tawọn ọlọpaa Saabo de naa niyẹn, pe awọn eeyan meji yii, Bonny ati Osuma ta tẹtẹ lọdọ Baba Puulu, ṣugbọn o jọ pe ko ko iwe tẹtẹ wọn lọ si hẹdikọta wọn, boya o ti ro pe awọn yẹn ko ni i jẹ. Afi bi esi tẹtẹ ṣe jade ti awọn yẹn jẹ, ni wọn ba bẹrẹ si i yọ ọ lẹnu pe ko fun awọn lowo awọn, owo ti ko tete ri san yii lo jẹ ko pokunso. Awọn ọlọpaa Saabo ti mu awon mejeeji ti wọn ta tẹtẹ yii o.