Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Beeyan ba jẹ ori ahun, to ba de ibi isinku ọkunrin olowo nla ati oloṣelu pataki ipinlẹ Ogun nni, Sẹnetọ Buruji Kashamu, lonii, ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹsan-an, oṣu kẹjọ, ọdun 2020 yii, tọhun yoo sunkun kikoro lai mọ ọkunrin naa ri tẹlẹ.
Niṣe lero n wọ bii omi ninu ọkan ninu awọn ile rẹ ti wọn sin in si n’Ijẹbu-Igbo. Ẹkun n pe ẹkun ran niṣẹ ni, bẹẹ lawọn eeyan to lọ rẹpẹtẹ, ti wọn n fọhun aro, kaluku n sọ ohun ti wọn padanu bi iku ṣe mu Baba Ṣẹri ti wọn n pe ni alaaanu mẹkunnu lọ.
Ọjọ Abamẹta, Satide, ni gudugbẹ ja lojiji, ti iroyin ọhun kọkọ n lọ labẹnu pe Ẹshọ Jinadu, bi wọn ṣe tun maa n pe Buruji, jade laye.
Awuyewuye lo kọkọ jọ tẹlẹ, bo tilẹ jẹ pe ọkunrin ọmọ Ijẹbu-Igbo naa ti wa lọsibitu nla kan niluu Eko tojọ mẹta, to n gba itọju lori aisan Korona to mu un.
Ṣugbọn ko sẹni to ro iku ro Buruji, ko sẹni to mọ pe erin yoo wo logun ọdun, nitori wọn ni o ti gbadun ti Korona yii, wọn ni awọn arun kan to ti wa lara rẹ tẹlẹ ni wọn n tọju. Afi bi ajanaku ṣe sun bii oke lojiji, ti Buruji Kashamu ṣe bẹẹ jade laye.
Alẹ Satide ni wọn ti gbe oku de siluu Ijẹbu-Igbo, wọn ti gbẹ koto silẹ nigba ti yoo fi di aarọ, bẹẹ lero n ya bii omi lati igba to ti di mimọ pe Ẹshọ Jinadu ti jade laye.
Nigba to si jẹ pe koto loore oku, ko tun si oore mi-in tawọn ara aye ri ṣe fẹni to ku ju ki wọn gbe e si koto naa lọ. Eyi naa lo fa a ti ẹbi Shodipẹ Kashamu ti Ijẹbu-igbo, nipinlẹ Ogun, ko ṣe fi isinku ọmọ wọn falẹ, ti wọn gbe e sin tẹkun-tẹkun lonii, ti i ṣe ọjọ Aiku.
Ni nnkan bii aago kan ọsan ku iṣẹju mẹtala ni wọn gbe Buruji wọ kaa ilẹ lọ, awọn aafaa agba nipinlẹ Ogun lo ṣeto isinku, Imaamu Mukaeel Shile Rufai lo ṣe waasi. Bẹẹ lawọn oloṣẹlu nipinlẹ Ogun bii Gomina Dapọ Abiọdun,Sẹnetọ Gbenga Kaka, Ọmọọba Ṣẹgun Adeṣẹgun, Sẹnetọ Lekan Mustapha atawọn mi-in wa nibẹ.
Ọpọlọpọ eeyan lo ti n ba wọn kẹdun nile awọn Buruji, bẹrẹ latori Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, Sẹnetọ Ibikunle Amosun. Ọtunba Gbenga Daniel tilẹ ni inu oun dun pe oun ti fori ji Kashamu ko too ku, bẹẹ ni Gboyega Nasir Isiaka naa fi ọrọ ibanikẹdun ranṣẹ.