O ma ṣe o, ẹran agbọnrin ni ọdẹ yii fẹẹ yinbọn fun loko, ọrẹ ẹ nibọn ba

Adewale Adeoye

Titi di asiko ta a n koroyin yii jọ lọwọ lọ jẹ pe inu ọfọ nla ati ẹdun ọkan lawọn ẹbi ọdẹ kan, Oloogbe Sunday Ijiọla, ẹni ọdun mẹtalelogoji, wa bayii. Eyi ko sẹyin bi ọrẹ oloogbe yii toun naa jẹ ogboju ọdẹ laarin ilu ṣe yinbọn pa a danu lasiko ti wọn n dẹgbẹ lọwọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, lagbegbe Pakoyi, niluu Owode-Ketu, nijọba ibilẹ Yewa North, nipinle Ogun.

ALAROYE gbọ pe awọn ogboju-ọdẹ mẹẹẹdogun lati ilu kekere kan ti wọn n pe ni Owode-Apesin, ni wọn kora wọn jọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu to kọja yii, ti wọn si gba inu igbo lọ gẹgẹ bii iṣe wọn lati lọọ pa ẹran igbẹ. Wọn rin inu igbẹ titi lọjọ naa, wọn ko ri ẹran gidi pa, bi wọn ṣe fẹẹ maa dari pada bọ sile ni wọn ba ri ẹran agbọnrin nla kan lojiji, inu wọn dun gidi, bẹẹ ni kaluku wọn n gbiyanju lati yinbọn fun ẹran naa, ṣugbọn niṣe ni ẹran naa fere ge e, o n sa lọ lẹlẹẹlẹ. Ki ẹran yii ma baa bọ mọ wọn lọwọ nitori ti wọn ko ri ẹran kankan pa lati aarọ ni wọn ba pin ara wọn si meji. Awọn kan lọọ dena de ẹran naa nibi ti wọn gbagbọ pe yoo gba kọja. Bi ẹran naa ṣe yọ si Atanda lojiji lo kọju ibọn si i, lo ba yinbọn fun un, n lawọn ẹlẹgbẹ rẹ yooku ba sare lọ sibi ti ẹran naa wo si lati lọọ gbe e, ṣugbọn iyalẹnu nla gbaa lọrọ ọhun jẹ pe oku Oloogbe Sunday ni wọn ba nilẹ, wọn gbiyanju lati tete gbe e lọ sileewosan ijọba kan to wa lagbegbe naa fun itọju, ṣugbọn loju ọna ni oloogbe naa ti dakẹ mọ wọn lọwọ.

Loju-ẹsẹ ti ọdẹ to yinbọn pa ẹlẹgbẹ rẹ yii ti ri ohun to n ṣẹlẹ lo ti sa lọ, kọwọ ọlọpaa ma baa to o.

Awọn ẹbi oloogbe naa ni wọn lọọ fiṣẹlẹ ọhun to awọn ọlọpaa agbegbe Eggua leti.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, S.P Ọmọlọla Odutọla, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹta, oṣu yii, sọ pe awọn n wa ọdẹ to yinbọn pa oloogbe naa bayii, ati pe awọn ọlọpaa agbegbe Eggua ti lọ sibi iṣẹle ọhun lati lọọ wo nnkan to ṣẹlẹ nibẹ.

Atẹjade kan ti wọn fi sita lori iṣẹlẹ ọhun lọ bayii pe, ‘’Awọn ọlọpaa agbegbe Eggua, nibi ti iṣẹlẹ ọhun ti waye ti lọ sibẹ, wọn ti ya fọto oku oloogbe naa, bakan naa ni awọn ẹbi oloogbe naa n bẹbẹ pẹ ki wọn jọwọ oku ọmọ awọn silẹ fawọn, kawọn le lọọ ṣeto isinku rẹ lọna tawọn fẹ. A n ṣewadii nipa iṣẹlẹ ọhun lọwọ,  a si maa too fọwọ ofin mu afurasi ọdaran ọhun laipẹ yii.

Leave a Reply