Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ọkunrin ọlọkada kan lo ti dero ọrun laaarọ Ọ̣̣̣̣̣̣̣jọru, Wẹsidee, ọsẹ yii, nigba to ja sinu koto to wa loju popo ilu Ikirun si Oṣogbo.
ALAROYE gbọ lati ileeṣẹ ajọ ẹṣọ oju popo nipinlẹ Ọṣun pe aago mẹfa aabọ aarọ niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.
Bi ọkunrin ọlọkada naa, ẹni to gbe obinrin kan lẹyin, ṣe de iwaju Averter Gas, lo dede kan koto ọhun lojiji, ko too di pe o le yiwọ kuro lọna, ẹpa ko boro mọ.
Ṣe ni oun ati obinrin to gbe sẹyin ṣubu soju titi. Oju-ẹsẹ la gbọ pe ọkunrin naa jade laye, ti ẹni to si gbe farapa yannayanna.
Ileewosan Orotunde, niluu Ikirun, ni wọn gbe obinrin naa lọ fun itọju, nigba ti wọn gbe oku ọlọkada sile igbokuu-si ibẹ.
Ọkada Boxer pupa to ni nọmba MEK 301 WV ti ọlọkada naa gun ti wa lagọọ ọlọpaa to wa niluu Ikirun pẹlu gbogbo awọn ẹru rẹ.