Adewale Adeoye
Awọn ọmọ ile kewu Almajiri meje ni wọn fa jade labẹ ilẹpa to wo lu wọn mọlẹ lọjọ Abamẹta, Satide, ogunjọ, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii. Awọn akẹkọọ ileewe alakọọbẹrẹ naa ti ori ko yọ lọwọ iku ojiji, ṣugbọn to fara pa yannayanna wa nileewosan ijọba agbegbe naa, nibi ti wọn ti n gba itọju lọwọ bayii.
ALAROYE gbọ pe akẹkọọ ileewe kan ti wọn n pe ni Malam Dan Umma Quranic School, to wa nileewe Bayan Science, to wa lagbegbe Badariya, nijọba ibilẹ Birnin Kebbi, nipinlẹ Kebbi, lawọn akẹkọọ ọhun. Adari agba ileewe naa lo ran wọn niṣẹ pe ki wọn lọọ bu ilẹpa wa ti wọn maa fi ṣatunṣe sara ileewe wọn ko too di pe ojo ọdun yii bẹrẹ.
Ẹnu bibu ilẹpa ọhun ni wọn wa ti ilẹpa naa fi ṣi lati oke, to si ya bo wọn mọlẹ, loju-ẹsẹ ni awọn meje ti ku patapata, nigba ti ọkan lara awọn akẹkọọ ọhun ṣeṣe gidi, ti wọn si ti gbe e lọ sileewosan ijọba to wa lagbegbe naa.
Malam Dan Umar, to jẹ alakooso ileewe naa to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ lọjọ Abamẹta, Satide, sọ pe abamọ nla gbaa niṣẹlẹ ọhun jẹ foun, nitori pe oun gan-an loun ran awọn akẹkọọ ileewe naa niṣẹ pe ki wọn lọọ bu ilẹpa wa lara okiti naa, ṣugbọn toun ko mọ pe o maa ja si iku fun wọn.
O ni, ‘loju-ẹsẹ ti iroyin ọhun ti kan mi lara pe ilẹpa tawọn akẹkọọ ileewe naa n bu wo pa wọn mọlẹ ni mo ti sare lọ sibẹ, ẹru Ọlọrun Ọba ba mi nigba ti mo ba oku awọn akẹkọọ meje labẹ ilẹpa naa, ṣugbọn ko sohun ti mo le ṣe si i. Aajo pe ki ojo ọdun yii ma ba gbogbo ileewe wa jẹ ni mo n ṣe lọwọ, mi o mọ pe ma a pada jẹbi nigbẹyin ni.