Ọwọ ti tẹ Sanni to maa n fọhun bii ẹbọra lati ṣe gbaju-ẹ fawọn araalu

Adewale Adeoye

Ọdọ awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Adamawa, ni gende kan, Ogbẹni Sani Mamman, ẹni ọdun mọkandinlogoji kan to n ṣe bii ẹbora laarin ilu lati fi ṣe gbaju-ẹ fawọn araalu nibi to n gbe wa bayii, o n ran awọn ọlọpaa lọwọ ninu iwadii wọn lori ẹsun ti wọn fi kan an.

Ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni ọwọ awọn agbofinro ipinlẹ naa tẹ ẹ lasiko to n ṣe bii ẹbora, ti yoo si maa lu awọn araalu  ni jibiti owo ati dukia wọn. Oriṣiiriṣii ohùn lo wa lẹnu rẹ,  eyi lo fi rọrun fun un lati maa lu awọn araalu naa ni jibiti kaakiri.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, S.P Suleiman Nguroje, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Abamẹta, Satide, ogunjọ, oṣu Kẹrin, ọdun yii, sọ pe awọn kan ti wọn mọ nipa iṣẹ ti ko bofin mu ti Sani maa n ṣe laarin ilu lo waa fọrọ rẹ to awọn ọlọpaa agbegbe ibi to n gbe leti, tawọn yẹn si tete lọọ fọwọ ofin mu un lẹyin ti wọn ri ẹri to daju ṣaka pe loootọ, ṣe lo n ṣe bii ẹbora lati maa fi ṣe gbaju-ẹ fawọn araalu.

Alukoro ni ọdọ awọn ti Sani wa lo ti jẹwọ pe loootọ loun maa n ṣe bii ẹbora lati fi lu awọn eeyan ni jibiti.

Leave a Reply