Kazeem Aderounmu
Titi di ba a ṣe n sọ yii ni awọn oṣẹre ati awọn afẹnifẹre n ba ọkan ninu awọn oṣere ilẹ wa, Iyabọ Ojo, kẹdun mama rẹ, Abilekọ Victoria Olubunmi Fetuga, to ku lẹni ọdun mẹtadinlaaadọrin.
Aarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ti i ṣe ọjọ kọkanlelogun, oṣu kọkanla yii, ni iya yii mi imi ikẹyin. Oju oorun la gbọ pe iya oṣere yii gba de oju iku.
Oṣere naa lo gbe e jade lori ikanni Instagraamu rẹ, nibi to ti kọ ọ sibẹ pe ‘‘Iya mi, wura mi, olutọnisọna mi, iyebiye mi, ṣe bi ẹ ṣe fẹẹ sọ fun mi pe o dabọ niyi? A ṣi fọrọ yii ṣawada ni bii ọjọ diẹ sẹyin, ti mo si n sọ bi o ṣe wu mi pe ki ẹ dagba, ki ẹ pẹ daadaa laye, ki ẹ si ri awọn ọmọ mi bi wọn ṣe maa dagba ti awọn naa yoo di ẹni ọkunrin ati obinrin. Ṣugbọn ẹ sọ pe rara… Ẹ ni ohun to dun ninu yin ju lọ ni pe mo layọ, inu mi si n dun… Ẹ ni ẹmi yin yoo maa ṣọ gbogbo wa, yoo si wa pelu wa. Ṣe emi ko kuku mọ pe ẹ ti n palemọ ati lọ.
Pẹlu gbigba ifẹ Ọlọrun, mo kede iku mama mi, Abilekọ Victoria Olubunmi Fetuga, ẹni to ku laaarọ kutu ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanlelogun, oṣu kọkanla, loju oorun rẹ lẹni ọdun mẹtadinlaaadọrin. Mama loootọ lẹ ti lọ, ṣugbọn awa ọmọ ati ọmọọmọ yin yoo ri i pe iranti yin wa titi lae. Gẹgẹ bẹ ẹ ṣe sọ fun wa pe ẹmi yin yoo wa pẹlu wa. Emi ni ọmọ yin to fẹran yin, Iyabọ Ojo.’’
Bi oṣere naa ṣe gbe ọrọ yii sori ikanni rẹ ni awọn eeyan ti n ṣe e ni pẹlẹ, ti wọn si n ba a daro lori iku ojiji to mu iya rẹ lọ.
Bo tilẹ jẹ pe oṣere naa ko sọ boya iya naa dubulẹ aisan, AKEDE AGBAYE gbọ pe o rẹ mama yii diẹ.