Iyawo senetọ kan atawọn mefa mi-in ku sinu ijamba ọkọ l’Ọrẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ko din leeyan meje ti wọn ku sinu ijamba ọkọ to waye loju ọna marosẹ Ọrẹ si Okitipupa lọsan-an ọjọ Ẹti, Furaidee yii.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ilu Abuja lawọn eeyan ọhun ti gbera lọjọ naa, ti wọn si balẹ si papakọ ofurufu to wa l’Akurẹ.

Lati ibẹ ni wọn ti ko ara wọn sinu awọn ọkọ meji to fẹẹ gbe wọn lọ siluu Igbọkọda, nijọba ibilẹ Ilajẹ, nibi ti wọn ti fẹẹ lọọ ba ọkan pataki ninu awọn aṣaaju ẹgbẹ APC nipinlẹ Ondo, Oloye Oluṣọla Oke, ṣe ayẹyẹ isinku iya rẹ.

Ko si iyọnu kankan fun wọn titi wọn fi kọja ilu Ọrẹ, nijọba ibilẹ Odigbo, asiko ti wọn de iyana Irele  ni wọn ni ọkọ akoyọyọ kan deede yawọ lojiji, to si lọọ kọlu ọkọ tiwọn loju ọna tirẹ.

Wọn ni loju ẹsẹ leeyan mẹrin ti ku ninu ọkọ Coaster nla to ṣaaju, ti awọn mẹta mi-in si tun ku ninu ọkọ ayọkẹlẹ to wa lẹyin.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, ọga ẹsọ oju popo nipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Ahmed Hassan, ni eeyan mẹrin pere (obinrin mẹta ati ọkunrin kan) ni wọn ku ninu ijamba ọkọ naa nigba tawọn mẹjọ fara pa yannayanna.

Ileewosan aladaani kan ti wọn n pe ni Pima eyi to wa niluu Ọrẹ, lo ni awọn ko gbogbo awọn to fara pa atawọn to ku sinu ijamba naa lọ.

Iyawo ọkan ninu awọn senetọ ilẹ wa tẹlẹ, Sẹnetọ Victor Ndoma Egba wa ninu awọn to padanu ẹmi wọn ninu ijamba naa.

Leave a Reply