Ọlawale Ajao
Inu ọfọ ni gbajugbaja oṣere tiata Yoruba nni, Bisọla Badmus, wa bayii pẹlu bo ṣe padanu iya ẹ laaarọ ọjọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Keji, ọdun yii.
Funra oṣerebinrin to dudu daadaa yii lo tufọ iku mama rẹ lori Instagraamu rẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, tiṣẹlẹ ọhun waye.
Ọrọ idagbere ati aro ni oṣere naa kọ sibẹ pe, “O di gbere o, Wura Mi…Titi digba mi-in ta a tun maa pade. Sun-un-re o, WURA MI.
O ti lọ lati sinmi ni, WURA MI. Titi aye ni n oo maa ṣaaro rẹ, IYA ADUNNI’’.
ALAROYE gbọ pe o ṣe diẹ ti aisan ti da mama naa gbalẹ, gbogbo itọju to si yẹ ni Bisọla atawọn ọmọ mama yii to ku fun un lasiko to wa laye, ṣugbọn aisan lo ṣee wo, ko sẹni to ri tọlọjọ ṣe. Iya oṣere naa pada jade laye.
Latigba ti oṣere to bi ọmọkunrin kan fun gbajumọ olorin Fuji ilẹ wa nni, Wasiu Ayinde, ti gbe ọrọ naa sita ni awọn ololufẹ rẹ, paapaa ju lọ awọn oṣere ẹgbẹ ẹ ti n ki oṣere naa ku ara fẹra ku mama rẹ to ku yii.
Lara awọn to ti ba Bisọla daro iku mama rẹ ni arẹwa oṣere to fi orileede Amẹrika ṣe ibugbe nni, Toyin Adewale, oṣere naa kọ ọ sabẹ fọto Iya Bisọla pe, ‘Eeeyaa, pẹlẹ o, Bisọla, ku ara fẹra ku, ki Ọlọrun tẹ wọn si afẹfẹ rere.
Bakan na ni Faithia Balogun, ẹni to kọ ọ sabẹ aworan naa pe ‘Mo ba ọ daro ti iku mama rẹ, ki Ọlọrun fun ọkan wọn nisinmi’.
Ẹlomin-in to tun kọ ọrọ idaro nipa iku Mama Bisọla queenoluwa. Oun kọ tiẹ pe, ‘Pẹlẹ o, ọkọ mi, jọwọ mu un mọra o, Ki Allah dari ẹsẹ rẹ ji i, ko si tẹ ẹ si Alujanna onidẹra.
Ọpọlọpọ awọn ololufẹ oṣere yii ni wọn ti n ba a daro iku mama rẹ.