O ma ṣe o, iyawo gomina yii ku lojiji

Ọrẹoluwa Adedeji

Iyawo gomina ipinle Akwa Ibom, Abilekọ Umo Eno, ti jade laye.

Obinrin naa mi imi ikeyin nileewosan, niwaju gbogbo awọn mọlẹbi rẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kerindinlọgbọn, oṣu yii.

ALAROYE gbọ pe o ti rẹ iyawo gomina yii o ṣe diẹ, ti wọn si ti n tọju rẹ ko too di pe nnkan yiwo l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu yii, ti obinrin naa si ki aye pe o digboose.

Nigba to n kede ipapoda obinrin naa, Kọmiṣanna fun eto iroyin nipinlẹ ohun, Ọgbẹni  Ini Ememobong ṣalaye pe, “Pẹlu ọkan to wuwo, la fi kede iku iyawo gomina ipinlẹ Akwa Ibom, Ajihinrere Patience Umo Eno, lẹyin aisan to ṣe e. Ninu alaafia lo mi eemin ikẹyin niwaju awọn mọlẹbi rẹ gbogbo.

Mọlẹbi yii ti gba ohun ti Ọlọrun wi nipa iṣẹlẹ naa,  bẹẹ ni wọn ṣi n beere fun àdúrà awọn èèyàn gbogbo ni asiko to le ti wọn n la kọja yii.

Ọpọlọpọ eeyan ni wọn ti n ba Gomina ipinlẹ Akwa Ibom, Pasitọ Umo Uno kẹdun iku ojiji to mu iyawo rẹ lo, ti wọn si n gbadura pe ki Ọlọrun rọ oun ati ìdílé rẹ loju.

Leave a Reply