Oloye Angela Nwaka Fọlarin to jẹ iyawo Sẹnetọ to n ṣoju Aarin Gbungbun lbadan nileegbimọ aṣofin agba, Tẹslim Fọlarin, ku lojiji.
Ko ti i sẹni to ti i le fidi iku to pa obinrin to jẹ agbẹjọro naa mulẹ. Ṣugbọn iroyin ta a gbọ lati ẹnu amugbalẹgbẹẹ sẹnetọ naa lori eto iroyin, YSO Ọlaniyi, fidi rẹ mulẹ pe United Kingdom lobinrin naa ku si lẹni ọdun mẹtadinlaaadọta lọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii.