Kazeem Aderohunmu
Pẹlu ibanujẹ lawọn oṣere tiata Yoruba fi kede iku ọkan pataki ninu wọn to ku lọjọ Ẹti, Furaidee.
Ọkanninu awọn oṣere naa, Kunle Afod, lo kọkọ gbe e sori ẹrọ agbọrọkaye, Instgiraamu, rẹ, nibi to kọ ̀ọ si Arabinrin Ẹniọla Kuburat naa ti dagbere faye pe o digbooṣe.
Ohun ti Kunle Afod, sọ ni pe aisan ranpẹ naa lo ṣe iya ọhun ti iku fi pa a.
Lara awọn ti wọn ti kẹdun iku obinrin yii lori instagiraamu Kunle ni Sikiratu Sindodo, Olaitan Sugar atawọn mi-in.