Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti bẹrẹ iwadii lori awọn ti wọn ṣa obinrin agbẹ kan, Titilayọ Gbadegeṣin ati ọmọ rẹ, Reuben, pa sinu oko wọn labule Alapata nijọba ibilẹ Ariwa Ifẹ.
Ọmọ bibi ilu Mọdakẹkẹ lobinrin naa, ṣugbọn abule Alapata, nitosi Ọyẹrẹ, lo ti n ta koko, ra koko, to si n ta obi, ra obi, ti aje si burẹkẹ diẹ si i lọwọ.
Idaji ọjọ Tusidee yii la gbọ pe awọn kan ṣa obinrin yii ati ọmọ rẹ pa sinu oko, ti ọrọ naa si fẹẹ di wahala pẹlu bi awọn ọdọ ilu Mọdakẹkẹ ṣe n korajọ lati fẹhonu han lori iku naa.
Ohun to mu ki ọrọ naa ka awọn ọdọ ọhun lara ju, gẹgẹ bi a ṣe gbọ ni pe ṣe lọmọ naa lọọ dagbere irinajo soke-okun to fẹẹ rin fun iya rẹ to fi lọ soko lọjọ naa, ṣugbọn ṣe lawọn apani naa da ẹmi rẹ legbodo.
Lẹyin ti awọn agbaagba ilu ati awọn agbofinro pẹtu sọkan awọn ọdọ naa ni wọn sọ pe ohun kan ṣoṣo to le jẹ ki ọrọ naa rodo lọọ mumi ni ki awọn ọlọpaa ṣewadii kiakia nipa awọn ti wọn wa nidii iṣẹlẹ laabi naa, ki wọn si fi oju wọn han faraye ri.
Alukoro fun agbarijọ awọn ọmọ ilu Mọdakẹkẹ, Venerable Debọ Babalọla, ṣe wi, ohun ti gbogbo ilu n fẹ bayii ni ki awọn ọlọpaa fi oju awọn amookunṣika naa le’de faraye ri.
O ni, “Inu abule yẹn lobinrin naa ti n ṣowo latọjọ to ti pẹ, Reuben si ni akọbi rẹ lọkunrin, o si ti mura irinajo soke-okun kiṣẹlẹ naa too ṣẹlẹ. Ko sẹni to le sọ bo ṣe ṣẹlẹ atawọn to wa nidii rẹ ju iwadii awọn ọlọpaa lọ.
“A gbagbọ pe awọn kan lara awọn ti wọn jọ n ṣowo labule yẹn maa mọ nipa iṣẹlẹ naa atawọn to wa nidii rẹ. Ijọba ibilẹ Ariwa Ifẹ ni abule Alapata wa, ṣugbọn awọn ọmọ Mọdakẹkẹ pọ nibẹ, abule Iṣọya to jẹ ti awọn Ifẹ sun mọ wọn.
“Inu ṣi n bi awọn eeyan wa gidigidi, ṣugbọn a mọ pe ti awọn ọlọpaa ba ṣiṣẹ wọn gẹgẹ bo ṣe yẹ lasiko, ko ni i pẹ rara ti aṣiri yoo fi tu, ti a si maa mọ ohun to ṣẹlẹ gan-an”
Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, waa fi ọkan awọn eeyan ilu naa balẹ pe iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ ọhun, ati pe laipẹ ni awọn yoo ridi ohun to ṣẹlẹ naa, ti gbogbo aye yoo si gbọ.
O ni awọn ti gbe oku obinrin naa ati ọmọ rẹ lọ sile igbokuu-si ti ileewosan OAUTHC, Ifẹ, bẹẹ ni awọn ti ba awọn ọdọ ilu Mọdakẹkẹ sọrọ lati gba alaafia laaye, ki wọn si fun awọn ọlọpaa laaye lati ṣiṣẹ wọn.