Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọ Aiku, Sunnde, ọṣẹ yii, ni Abilekọ Fatima Ranti, ti agboole Kọla, ni agbegbe Asunara, lẹgbẹẹ Balogun Fulani, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, ji loju orun, to si lọọ ko si kanga kan lagboole ọhun.
ALAROYE, gbọ pe Ranti ti lọkọ to ti bi ọmọ pẹlu, ṣugbọn to ti figbakan ni arun ọpọlọ diẹ, wọn lo ji loruganjọ ni, o si jade sita, ẹni kan to jẹ agba ni agboole naa sọ pe oun ri i nigba to n jade lọ, sugbọn oun ro pe o fẹ lọọ tọ nita ni, alọ lo ri, ko ri abọ rẹ, lo ba figbe ta, ti wọn si bẹrẹ si i wa a kiri. Nigba ti ilẹ mọ ni wọn ri oku ẹ ninu kanga.
Wọn pe ajọ panapana ẹka tipinlẹ Kwara, ti wọn si yọ oku ẹ jade ninu kanga naa. Olori agboole ọhun ti wọn n pe ni Alaaji Asunara ni wọn gbe oku Ranti le lọwọ. Adari ajọ panapana nipinlẹ Kwara, Ọmọọba Falade John Olumuyiwa, ti waa rọ awọn eeyan ipinlẹ naa ki wọn maa wa ni toju tiyẹ ti aparo fi n rina, ki wọn si maa kiyesi awọn alaabagbe wọn lati dena irufẹ iṣẹlẹ abami bayii.