Aderounmu Kazeem
Agbọ-sọgba-nu ni iku ọkan ninu awọn oṣere Fuji nilẹ wa, Alaaji Tajudeen Iṣọla, ti gbogbo eeyan mọ si Ashanti Sholey, to jade laye ṣi n jẹ fun ọpọ eeyan to gbọ nipa rẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii.
ALAROYE gbọ pe ko ti i sẹni to le fidi iku to pa ọmọ bibi Isalẹ Eko, nipinlẹ Eko, yii mulẹ. Ohun ti awọn eeyan kan gbọ naa ni pe o ku.
Orileede France lọkunrin onifuji to gbajumọ daadaa yii n gbe lẹyin to kuro ni Naijiria, o si ti wa nibẹ to ọjọ mẹta. O ti kọrin daadaa ni Naijiria, to si gbajumọ laarin awọn onifuji ẹgbẹ ẹ, ko too maa lọọ gbe oke-okun.
Ọpọ awọn to mọ ọkunrin naa daadaa ni wọn ti n daro rẹ, ti iku rẹ si ba ọpọ awọn to gburoo rẹ laipẹ yii lojiji, bẹẹ lo n ṣe wọn ni kayeefi.