Ọkẹ aimọye dukia to to miliọnu naira lo ṣofo nibi iṣẹlẹ ina kan to jo ṣọọbu mẹfa ni agbegbe Geri-Alimi, niluu Ilọrin, lowurọ kutu, ọjọ Aiku, Sannde, ọṣẹ yii. ALAROYE gbọ lẹnu arabinrin kan ti oun naa ni ninu awọn ṣọọbu to jona ọhun pe ni nnkan bii aago marun-un idaji ni ina ọhun sẹ yọ, ti gbogbo dukia to wa ninu awọn ṣọọbu naa si jona raurau ki ileeṣẹ panapana too de síbi iṣẹlẹ ọhun.
Bakan naa, Arabinrin Adetoro Anifat, to n ta awọn aṣọ ọkunrin ati tobinrin ti gbogbo ọja rẹ jona naa ṣalaye fawọn oniroyin pe gbogbo ọja ti oun ṣẹṣẹ ra lati ta fun ọdun Keresimesi lo jona patapata. O ni ọja to wa ninu ṣọọbu toun nikan to miliọnu mẹta naira.
Ẹlomiiran to tun ba wa sọrọ, Ọgbẹni Owolabi Akeem, to n ta oogun awọn ounjẹ adiẹ naa salaye pe gbogbo ọja to wa ninu ṣọọbu oun naa lo jona raurau, toun ko si ti i mọ igbeṣẹ to kan ninu aye oun bayii. Gbogbo awọn ontaja nibi ṣọọbu naa ti waa rọ ijọba ipinlẹ Kwara ati awọn ẹlẹyinju aanu lati dide iranwọ si wọn lori bii wọn yoo ṣe rowo bẹrẹ ọja miiran.