O ma ṣe o! Ọmọ Naijiria meji ku sibi ti wọn ti n ṣiṣẹ laada ni Mẹka

Monisọla Saka

Meji ninu awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria ti wọn ti kalẹ siluu Mẹka, lorilẹ-ede Saudi Arabia, fun Iṣẹ Hajji ọdun 2024, ni wọn ti dagbere faye.

Awọn oloogbe mejeeji ọhun, ọkunrin kan, ati obinrin kan, ni wọn wa lati ipinlẹ Kebbi, lorilẹ-ede Naijiria.

Ninu atẹjade ti Akọwe iroyin ileeṣẹ to n ri si eto irinna si orilẹ-ede Saudi nilẹ Naijiria, National Hajj Commission of Nigerian (NAHCON), Muhammad Musa, fi sita lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, lo ti sọrọ naa di mimọ.

Ẹni akọkọ to kọkọ jẹ Ọlọrun nipe ni Arabinrin Tawakalitu Alako, nigba ti ẹni keji toun jẹ ọkunrin n jẹ Mohammad Suleman.

Garba Takware, ti i ṣe alaga awọn igbimọ eleto Hajj nipinlẹ Kebbi, toun naa fidi iṣẹlẹ yii mulẹ sọ pe Hajia Tawakaltu Busare Alako, to wa lati ipinlẹ Kebbi yii ko ṣaisan, ounjẹ lo fẹẹ lọ gba ni otẹẹli ti wọn fi wọn wọ si to fi ṣadeede ṣubu lulẹ lojiji lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, to si ku.

O ni, “Otẹẹli ti wọn de si ni Mẹka lo ti fẹẹ lọọ gba ounjẹ nigba to ṣubu lojiji. Ṣaaju akoko naa, koko ni ara rẹ le.

A sare gbe e digbadigba lọ sileewosan, amọ ko le gbe apa ati ẹsẹ mọ ka too debẹ”.

“Gbogbo eto yooku lo n lọ gẹgẹ bi a ṣe ti la a kalẹ. Latibi ounjẹ, de ile gbigbe ati eto ilera. Amọ ti iṣẹlẹ buburu yii wa lati ọdọ Ọlọrun Ọba, o si ju agbara tiwa lọ”.

Lẹyin aisan ranpẹ, ni ẹni keji, iyẹn Muhammad Suleman, to wa lati ijọba ibilẹ Argungu, nipinlẹ Kebbi, bakan naa dagbere faye niluu Mẹka.

Alaaji Faruk Aliyu-Enabo to jẹ alaga igbimọ to n mojuto igbaye-gbadun ileeṣẹ Hajj ipinlẹ Kebbi, lo fọrọ naa sita fawọn oniroyin niluu Mẹka, lọjọ Sannde.

O ni, “Lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni oloogbe dakẹ lẹyin aarẹ diẹ, a si ti ṣeto isinku ati adua fun un ni mọṣalaṣi Haram, ni Kaaba. A ti sin in ni ilana ẹsin Musulumi lọjọ to mi eemi ikẹyin yii.

“Lorukọ ijọba ibilẹ Kebbi atawọn eeyan ipinlẹ naa pata, mo ki awọn ẹbi oloogbe ku ara fẹra ku eeyan wọn.

A gba a laduura si Ọlọrun Ọba, ko ba wa fori gbogbo aṣiṣe rẹ jin in, ko si gba oun atawọn oku yooku si alujanna onidẹra”.

O rọ mọlẹbi oloogbe lati gba a gẹgẹ bii amuwa Ọlọrun, nitori ko si ẹda kan ti yoo lo kọja igba ti Ẹlẹdaa ti da fun un.

Ka ranti pe lati Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ karundinlogun, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni awọn alalaaji ilẹ Naijiria ti n gbera lọ siluu Mẹka, ni ipalẹmọ fun iṣẹ hajj ọdun yii.

Ninu awọn bii ẹgbẹrun marundinlaaadọrin (65,000) ti yoo lọ lati Naijiria lọdun 2024 yii, awọn ẹgbẹrun lọna ogun ati merinlelaaadọjọ (20,154) ni wọn ti balẹ si Mẹka.

 

Leave a Reply