O ma ṣe o: Wọn yinbọn pa Risikatu alaboyun n’Ikorodu

Kazeem Adeounmu

Lojiji ni obinrin alaboyun kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Risikatu ku niluu Ikorodu, awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ni wọn yinbọn pa a.

Lọwọ aṣalẹ ni deede aago mẹjọ ni wọn sọ pe awọn janduku ọmọ egbẹ okunkun, Ẹyẹ ati Aiye. bẹrẹ ija niluu Aleke. Nibi ti wọn ti n fi ibọn lera wọn kiri ni wọn ti yinbọn fun obinrin naa ninu ọja to wa niluu ọhun, loju-ẹsẹ ni wọn sọ pe o ba iṣẹlẹ ọhun lọ.

Ọmọ ipinlẹ Kwara ni wọn pe Risikatu ti wọn pa yii, bẹẹ iya ọlọmọ meji ni.

Baalẹ ilu Aleke, Oloye Adeniyi Okemati ti ba awọn oniroyin sọrọ, alaye to si ṣe ni pe, bo tilẹ jẹ pe awọn ranṣẹ pe awọn ọlọpaa, sibẹ ki wọn too de niṣẹlẹ buruku ọhun ti waye.

Bẹẹ lo fi asiko yii ke si ijọba lati wa ojuutu si bi awọn janduku yii ṣe n fi ọpọ igba da wahala silẹ lagbegbe ọhun, ti wọn si maa n ṣe ọpọ ẹmi ati dukia lofo

A gbọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ti gbe oku ẹ fun awọn mọlẹbi ẹ, ati pe wọn ti gbe e lọ si ilu ẹ nipinlẹ Kwara.

 

Leave a Reply