Ọgbara ojo to rọ lanaa gbe ọmọ meji lọ ni Ketu

Wọn ṣii n wa awọn ọmọ meji kan lagbegbe Ketu ni ilu Eko o, inu ibanujẹ si ni gbogbo ara adugbo naa wa, nitori wọn mọ pe ọgbara ojo lo gbe awọn ọmọ naa lọ. Ni bii aago mẹjọ alẹ ana, lasiko ti ojo naa n rọ wii wii ni iṣelẹ naa ṣelẹ ni popo Oyebajo ni Ketu.

Ajọ to n ri si ọrọ iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ eko, LASEMA, sọ ninu alaye wọn lori  awọn nipa awọn ohun to ṣẹlẹ lasiko ojo naa pe ipe pajawiri n iwọn pe awọn lati adugbo naa ti awọn si sare lọ. Ọga agba LASEMA yii, Omọwe Olufẹmi Oke-Ọsanyintolu, sọ pe nigba tawọn eeyan oun debẹ ni wọn gbọ pe ni bii aagọ mẹjọ alẹ ni ọgbara ojo gba awọn ọmọ mejeeji lọ, ati pe awọn n ṣe gbogbo aapọn lati ri wọn fa yọ, tabi mọ ibi ti ayalu omi naa gbe wọn lọ.

Koda, awọn ileeṣẹ panapana Eko ati awọn ẹka gbogbo to n da si iru iṣẹlẹ ojiji bayii ni wọn wa nibẹ lati ri i pe wọn ri awọn ọmọ naa wa jade.

 

Leave a Reply