Gbenga Amos, Ogun
Epe rabandẹ rabandẹ lawọn eeyan n gbe baale ile ẹni ọdun mẹrindinlọgọta yii, Ọgbẹni Oluṣẹgun Oluwọle, ṣẹ, bẹẹ ni wọn n bu u loriṣiiriṣii, latari bọwọ awọn ọlọpaa ṣe tẹ pẹlu ẹsun pe o ki ọmọ bibi inu ẹ ti ko ju ọdun mẹtadinlogun mọlẹ, o si fipa ba a laṣẹpọ.
Adugbo kan ti wọn n pe ni Amọlaṣọ, nitosi Kutọ, niluu Abẹokuta, niṣẹlẹ naa ti waye gẹgẹ bi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Ogun, SP Abimbọla, ṣe ṣalaye ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹsan-an yii, lori iṣẹlẹ ohun.
Abimbọla ni ọmọbinrin ti wọn forukọ bo laṣiiri naa lo waa fẹnu ara ẹ ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fawọn ọlọpaa ni ẹka ileeṣẹ wọn to wa ni Ibara, awọn ẹṣọ alaabo So-Safe kan tọmọ naa ti kọkọ fẹjọ baba ọran yii sun si tẹle e de teṣan.
Ninu ẹjọ to ro, o ni nnkan bii aago mọkanla aabọ alẹ ọjọ, Abamẹta, Satide, ọjọ kẹwaa, oṣu yii, ni baba oun yọ kẹlẹ wọnu yara toun n sun si, o lọwọ ti pa, ẹsẹ ti pa nigba naa, gbogbo araale yooku ti sun, ni baba naa ba ṣi oun laṣọ, o si fọwọ di oun lẹnu, o ni niṣe loun maa pa oun danu toun ba fi le pariwo tabi sọ fẹnikan, bẹẹ ni Oluṣẹgun ṣe fipa ba oun laṣepọ.
Kia ti DPO teṣan Ibara gbọrọ yii lo ti paṣẹ fawọn ọmọọṣẹ ẹ ki wọn lọọ mu baba naa, wọn si fi pampẹ ofin gbe e, o di tọlọpaa.
Wọn ni afurasi yii o jiyan rara, o jẹwọ pe loootọ loun huwa laabi naa, amọ ki wọn foriji oun, tori ọmọ mẹfa loun ni, oun o tiẹ le sọ pato ohun to rọ lu oun toun fi ba ọmọ oun sun bii obukọ.
Amọ ṣa, ọrọ yii ti detiigbọ Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle si ti paṣẹ pe ki wọn fi baba kibaba yii ṣọwọ sawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lẹka ti wọn ti n ṣewadii iwa ọdaran abẹle.
Bakan naa ni wọn ti gbe ọmọbinrin naa lọ ileewosan jẹnẹra fun ayẹwo ati itọju iṣegun.
Wọn lafurasi ọdaran yii maa fara han niwaju adajọ laipẹ.