Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku nilẹ yii, (EFCC), ti mu oyinbo Chinese kan, Gang Deng, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn, fẹsun pe o n wakusa lọna aitọ niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara.
Ninu atẹjade kan ti Alukoro ajọ naa, Wilson Uwujaren, fi sita to tẹ ALAROYE lọwọ lọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, sọ pe lọjọ Ẹti, Furaidee, ni ọwọ tẹ Deng, pẹlu awọn ohun alumọọni to lọọ wa lọna aitọ lai gba iwe aṣẹ lọwọ awọn alaṣẹ, ti wọn si ri ọkọ tirela to fi n ko ẹru naa gba lọwọ rẹ. O tẹsiwaju pe ajọ naa yoo foju oyinbo yii bale-ẹjọ laipẹ lẹyin ti wọn ba pari gbogbo iwadii.
Tẹ o ba gbagbe, ninu oṣu to kọja yii, ni ajọ ọhun ati sifu difẹnsi ṣiṣẹ papọ, ti wọn si mu awọn mẹtala kan lagbegbe Kakafu, nijọba ibilẹ Pategi, nipinlẹ naa, fẹsun pe wọn n Wakusa lọna aitọ kọwọ too tun tẹ oyinbo Chinese, lọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii, fun irufẹ ẹsun kan naa.