Ẹ wo Oluwaṣeun to n fibọn onike jale n’Idiroko

Gbenga Amos, Ogun

Ọjọ gbogbo ni tole, ọjọ kan ni tolohun. O pẹ ti ọdọkunrin ẹni ọdun mejilelogun kan ti n fi ibọn onike jale lagbegbe Idiroko, nipinlẹ Ogun, tawọn eeyan ko si mọ pe ayederu ibọn lo fi n ṣeru ba wọn. Ṣugbọn iwa ọdaran naa ti sọ ọ dero ahamọ bayii, nigba tọwọ palaba rẹ segi.

Ọga agba awọn ẹṣọ alaabo So-Safe nipinlẹ Ogun, Kọmanda Sọji Ganzallo, lo sọrọ yii di mimọ ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹsan-an ta a wa yii.

Ganzallo ni ni nnkan bii aago meji kọja iṣẹju diẹ lọwọ awọn ọmọọṣẹ oun ti wọn wa lagbegbe ijọba ibilẹ Ipokia ba afurasi ọdaran yii lọjọ Ẹti, Furaidee, to ṣaaju.

Wọn ni niṣe ni Oluwaṣeun, to n gbe Agboole Olorogbo, lagbegbe Aṣheko/Ibatẹfin, nijọba ibilẹ kan naa, mura bii ero to fẹẹ gun ọkada, o duro sẹgbẹẹ ọna, o si da ọlọkada kan duro, Bamidele Mujeeb lorukọ tiyẹn n jẹ, o ni ko gbe oun lati Opopona Afẹriku, ni Idiroko, to duro si lọ si Opopona Ọbalana, lọna Bebe, ọna ti wọn n tọ jade si orileede olominira Bẹnẹ.

Ṣe awọfẹlẹ bonu ko jẹ ka rikun aṣebi, bi wọn ṣe n lọ lọna, bẹẹ ni Oluwaṣeun n dari ọlọkada pe ko ya sọna mi-in, ti wọn ba ti rin siwaju diẹ, aa tun ni ko ya sibi kan, lai mọ pe niṣe ni jagunlabi n dọgbọn yọ ibọn to fi sabẹ aṣọ.

Lojiji lo ni kọlọkada naa duro, biyẹn si ṣe duro, niṣe lafurasi yii fa ibọn yọ si i, o ni ko mu eyi to ba fẹ ninu ko fi ọkada ẹ silẹ ko tete maa sa lọ, abi koun yinbọn pa a.

Bi eyi ṣe n ṣẹlẹ lọwọ, Oluwaṣeun ko mọ pawọn ẹṣọ So-Safe ti wọn n patiroolu kiri agbegbe naa ti wa lọọọkan ti wọn ṣakiyesi ohun to n ṣẹlẹ, kia ni wọn si ti kan wọn lara, ni wọn ba mu un pẹlu ibọn ọwọ ẹ. Igba ti wọn yẹ ibọn naa wo laṣiiri tu pe ibọn iṣere ọmọde, ibọn onike, lo fi n jale kiri.

Nigba ti wọn wọ ọ de ọfiisi wọn, afurasi naa jẹwọ pe loootọ loun fẹẹ ja ọkada naa gba, ati pe o ti pẹ toun ti n fibọn onike ọhun jale lagbegbe naa, o ni niṣe loun maa n ta awọn eru ole naa ni gbajo, toun si n fowo ẹ jẹun.

Ganzallo lawọn ti fa oun ati ọkada to fẹẹ ji, ati ọlọkada naa, le awọn ọlọpaa ẹka ileeṣẹ Idiroko lọwọ, ki wọn le tubọ ṣewadii, ki wọn si gbe igbesẹ ofin lori ẹ.

Leave a Reply