Ẹyin ọkunrin gidi da, Ẹniọla Badmus loun n w’ọkọ o

Faith Adebọla, Eko

Bawọn apọn ti wọn n wa iyawo, atawọn ọkunrin ti wọn n ṣaroye pe awọn o rẹni fẹ, ba tete gba anfaani kan to ṣi silẹ lọdọ gbaju-gbaja oṣere tiata ilẹ wa kan mu, ti wọn tete kan si Ẹniọla Badmus lori aago tabi lori ikanni ayelujara ẹ lai fakoko ṣofo, o ṣee ṣe ki tuu ge fọọ fun wọn o, tori obinrin arẹwa to lomi lara tẹlẹ, ṣugbọn to ti waa di lẹpa bayii, ti kede pe oun n wa ọkọ o, kawọn ọkunrin gidi, awọn fain bọbọ lanu ba oun sọrọ, ki wọn jẹ koun mọ bo ṣe n lọ lọkan wọn.

Eyi ko ṣẹyin bawọn ọkunrin ṣe n kọ oriṣiiriṣii ọrọ ifẹ sori fọto to gbe sori Instagraamu rẹ, ti wọn si n ṣe ẹda awọn fọto naa, ti wọn n tun fọto naa ya si nla tabi kekere, ti wọn si n fi wọn dara oriṣiiriṣii bo ṣe wu wọn.

Kinni yii ko ṣẹṣẹ maa ri bẹẹ o, ṣugbọn Ẹniọla ti lohun toun n reti kọ leyi ti wọn n ṣe yẹn, o ni kawọn ti wọn nifẹẹ soun ba oun sọrọ loun fẹ, ki i ṣe ki wọn kan maa fi fọto oun dabira, tabi ki wọn maa dọgbọn kọ ọrọ sabẹ wọn.

Ninu ọrọ kan ti “Gbogbo Big Gẹz”, gẹgẹ bawọn kan ṣe maa n pe e, gbe sori ikanni Instagiraamu ẹ lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide to lọ yii lo ti ni: “Ti mo ba wọ yin loju, ẹ dẹnu ifẹ kọ mi. Ẹ yee ṣe fọto mi bo ṣe wu yin, tori o n dun mi o. Ẹ sọrọ jade, ẹ ma tun fọto mi ya si oriṣiiriṣii, tori mo n mọ ọn lara o.”

O tun sọ pe: “Mo gbọ pe ọrọ mi ni wọn n sọ lọwọlọwọ bayii, wọn ni ọrọ mi lo wa lẹnu awọn eeyan kaakiri, ṣe loootọ ni ṣa?”

Bẹẹ, loootọ, bi wọn ba daṣa ‘ẹni ti wọn n sọ’ fun Ẹniọla Badmus lasiko yii, tiẹ to bẹẹ. Yatọ si bi ẹnu ṣe n ya ọpọ eeyan sawọn fọto tuntun tobinrin naa n gbe sori ikanni ẹ, to ṣafihan bo ti ṣe din isanra jọkọtọ ẹ ku daadaa, ti Wule Bantu waa di lẹpa, to si tun jẹ arimaleelọ, bii iṣẹ iyanu nla kan ni irisi obinrin naa ri loju awọn ololufẹ ẹ, agaga awọn ti wọn mọ ọn latilẹ wa.

Ọrọ mi-in to tun n lọ nigboro nipa Ẹniọla Badmus ni ti ile agberin to ṣẹṣẹ tẹ irawọ oṣere naa lọwọ, iyẹn ọkọ ayọkẹlẹ to fi ṣe ẹbun ayẹyẹ ọjọọbi ẹ laipẹ yii.

Gbogbo ọjọ keje, oṣu Kẹsan-an, l’Ẹniọla maa n ṣayẹyẹ ọjọọbi ẹ, tori ayajọ ọjọ naa lo n le ọdun kan si i loke eepẹ. Iranti ọjọọbi naa ti Wule Bantu ṣe lọdun 2022, iyẹn Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja, ni ẹbun ọkọ ayọkẹlẹ tuntun, Mercedes-Benz GLE 450 SUV igbalode too lọwọ, amọ iyatọ to wa nibẹ ni pe ki i ṣe alejo, tabi ololufẹ ẹ kan lo ra ọkọ naa fun un o, Ẹniọla lo ra ọkọ ẹ, oun lo si fun ara ẹ lẹbun ọjọọbi ọhun.

Lori ikanni Instagiraamu ẹ lori ẹrọ ayelujara, nibi to ti kede ọkọ tuntun naa, Ẹniọla kọ ọ sibẹ pe: “Ẹbun ọjọọbi ti mo fun ara mi ree o…. Mi o tiẹ mọ ibi ti n ba ti bẹrẹ, ṣugbọn mo ṣaa mọ pe mo gbiyanju ṣa…. Iṣẹ aṣelaagun mi lo mu eleyii wa o, gbogbo yin lẹ si le jẹrii si i.”

Bi Ẹniọla ṣe kọ ọrọ yii tan lo gbe fọtọ ara ẹ ṣẹgbẹẹ mọto naa, o si gbe e soke ọrọ ọrọ to kọ ọhun. Oju-ẹsẹ lawọn ololufẹ rẹ ti bẹrẹ si i kan saara si i, wọn lawọn ba a yọ fun ti ọjọọbi ẹ, wọn si tun ki i ku oriire fun ti ọkọ ayọkẹlẹ tuntun to ṣẹṣẹ ja lailọọnu ẹ, wọn ni oriire naa aa ba a kalẹ, wọn si ṣadura fun un. Bẹẹ lawọn oṣere tiata ẹlẹgbẹ rẹ, atawọn olorin ko gbẹyin, kaluku wọn lo kọ ọrọ ikini sori ikanni ENIBAD, inagijẹ tuntun to loun n jẹ.

Ninu lẹta kan ti arẹwa obinrin naa kọ lori ọjọọbi ọhun, o ni inu oun dun pe oun ṣi rẹwa, o loun rẹwa lasiko yii ju boun ṣe ri ni ọjọọbi ọdun to kọja lọ, oun si tun mọ riri bi Ọlọrun ṣe bukun oun pẹlu ẹmi ifarada, ifẹ, ọkan akin ati okun lati fi ṣiṣẹ. O loun ranti ọgọọrọ awọn ololufẹ oun ti wọn n ti oun lẹyin, o lawọn lejika ti ko jẹ kaṣọ o ja bọ, o si dupẹ gidigidi lọwọ wọn.

Ọkan-o-jọkan fọto ati fidio to rẹwa l’Ẹniọla ya sori ikanni rẹ, oriṣiiriṣii sitai lo fi ya wọn, bo ṣe n kuru, lo n ga, ninu awọn mi-in, bo ṣe n yọdi sẹyin lo n ti aya ati ọyan siwaju ninu omi-in, o ni gbogbo ẹ, oun n yayọ ọjọọbi oun ni.

Amọ lọjọ kẹta

Leave a Reply