O ma waa ga o! Wọn tun ji agbẹ mi-in gbe n’Igangan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Lẹyin ọjọ mẹta ti wọn ji gbajumọ oniṣowo epo rọbi gbe niluu Idere nitosi Igboọra ni ipinlẹ Ọyọ ki wọn too pada yinbọn pa a, wọn tun ti ji ọkunrin agbẹ kan, Nosiru Aderoju, gbe niluu Igangan ni ipinlẹ yìí kan naa.

Ta o ba gbagbe, lọsẹ to lọ lọhun-un ni wọn ji agbẹ kan tó n jẹ Oluwọle  Agboọla gbe ninu oko ẹ lọna Ibadan siluu Ọyọ.

Ni nnkan bíi aago mẹjọ aabọ alẹ lawọn ajinigbe ọhun lọọ ka Alhaji Aderoju mọ itosí ile ẹ ti wọn sì gbé e bi igba ti aṣa ba gbe ọmọ adiẹ.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, lasiko ti ọkunrin agbẹ náà n dari lọ sile lẹyin to kí irun aago mẹjọ alẹ tan lawọn amookunṣika ẹda naa lọọ da a lọna ti wọn si ji i gbe nitosi ilé ẹ lOke agbẹdẹ niluu Igangan.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, alaga ẹgbẹ idagbasoke ilu Igangan, Ọgbẹni Ọladokun Ọladiran sọ pe o jọ pé awọn obayejẹ ẹda naa ti n ṣọ Ọgbẹni Aderoju tipẹ, ti wọn sì n tẹle e kiri tẹlẹ ki wọn too papa ri i mu.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “awọn eeyan ṣakiyesi awọn àjèjì kan bíi Fulani ni mọṣalaṣi to (Alhaji Aderoju) ti kirun lalẹ ana yẹn ṣugbọn wọn ko fura pe iṣẹ ibi ni won waa ṣe. O ṣe é ṣe kó jẹ pe awọn èèyàn yẹn ni wọn ṣọ ọ dé mọsalaṣi ki wọn tóo tun ti ibẹ tẹle e de ọna ile ẹ ti wọn ti jí i gbe.

Agbẹnusọ fún ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ SP Olugbenga Fadeyi fidi iṣẹlẹ yìí mulẹ, o ni awọn agbofinro ti bẹrẹ iṣẹ lati yọ ọkunrin agbẹ naa kuro nigbekun awọn ajinigbe ọhun ki wọn sì mú awọn afurasi ọdaran naa.

Leave a Reply