Stephen Ajagbe, Ilorin
Iyaale ile ẹni ọdun mejidinlogoji kan, Ajayi Fọlaṣade, to wa ni kilaasi JSS2, nileewe girama Ilọrin Grammar School, IGS, ni o maa n wu oun bawọn ọrẹ ati ẹgbẹ oun ṣe maa n sọ ede oyinbo, idi niyẹn toun fi pada sileewe.
Nigba to n ba ALAROYE sọrọ ninu kilaasi rẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, Fọlaṣade ni ileewe toun lọ nigba toun kere, bii ẹni ṣere lọ lasan ni. O ni oun ko tilẹ kọbi ara si iwe kika nigba naa nitori pe ki i saaba si aaye foun.
O ni ṣaaju akoko yii, oun ti lọ sileewe ẹkọ agba nibi toun ti gba iwe-ẹri pamari sisi (Pry 6).
Fọlaṣade ni o wu oun lati mọ iwe si i, paapaa lati le maa ka ede oyinbo, idi toun fi ro o pe o yẹ koun pada sileewe ree lai fi ti ọjọ ori ṣe.
O ni ohun to tubọ mu ifasẹyin ba eto ẹkọ oun ni pe ọdọ aburo baba oun loun gbe ni kekere, iyẹn ko si lowo lọwọ lati ran oun nileewe nigba naa.
“O maa n dun mi ti mo ba ri awọn ẹgbẹ mi nigba naa. Wọn maa maa sọ oyinbo, wọn maa maa kawe, ṣugbọn emi o mọ ọn ka. Ti mo ba tiẹ gbiyanju lati ka a gan-an, mi o le ka a jinna ti ma a fi dakẹ. Mo maa n wo wọn bi wọn ṣe n kawe ti wọn si n sọ oyinbo.”
Obinrin ọhun ni awọn ẹbi oun ko ti i mọ pe oun ti pada sileewe, oun kan fẹẹ ṣe idanwo JSS3 na, ṣugbọn oun ni lati mọ ohun toun yoo ṣedanwo le lori lo mu oun pada sileewe.
O ni ko ti oun loju rara boun ṣe n jokoo laarin awọn ọmọde toun le bi lọmọ, o ni koda, iwuri ni wọn jẹ foun, nitori pe boun ko ba ri nnkan ka, awọn ọmọ kilaasi yii lo maa ka a foun.
O ṣalaye pe latigba toun ti de ileewe naa loun ti di a-pe-waa-wo fawọn akẹkọọ kilaasi yooku. O ni ọpọlọpọ igba ni wọn maa n wa lati kilaasi wọn lati waa yọju wo oun loju ferese.
O ni gbogbo awọn olukọ ileewe naa lo n ṣe daadaa soun, ti wọn si maa ran oun lọwọ ni gbogbo asiko toun ba nilo iranlọwọ.
Nigba to n dahun ibeere lori ohun to ni lọkan lati ṣe lọjọ iwaju to ba pari ẹkọ rẹ, obinrin naa ni ọjọ ori oun ko le jẹ koun sọ ohun toun fẹẹ ṣe, ṣugbọn oun fi ohun gbogbo le Ọlọrun lọwọ lati tọ irinajo oun.
Arabinrin Busari Motunrayọ to jẹ olukọ fun Fọlaṣade ṣapejuwe obinrin naa gẹgẹ bii oniwapẹlẹ. O ni o rẹ ara rẹ silẹ lati maa ba awọn ọmọ kilaasi rẹ ṣe, ko si jẹ kawọn mọ pe iya loun jẹ fun awọn ọmọ naa.
Busari ṣalaye pe iyatọ ti de ba obinrin naa lọwọ asiko to de ileewe ọhun. O nigba kan, ko le kọ tabi ka iwe, ṣugbọn ni bayii o ti le kọ ati ka iwe diẹdiẹ, koda o ti le sọ oyinbo diẹ, yatọ si bo ṣe wa lati ileewe ẹkọ agba to lọ.
Giiwa kilaasi akọkọ nileewe girama (JSS) nileewe IGS, Abdulrahman Zubair Akẹyẹde, ṣalaye bi obinrin naa ṣe de ileewe ọhun, o ni ọfiisi ẹka to n mojuto eto ẹkọ nipinlẹ Kwara lo gba de ileewe IGS.
O ni lati ọdọ Abilẹkọ Ṣhagaya ni obinrin ọhun ti de ọdọ akọwe agba ileeṣẹ ijọba to n mojuto eto ẹkọ. O ni o sọ fun wọn pe oun nifẹẹ lati lọ sileewe, o si ni ileewe IGS lo sun mọ ọdọ oun.
“Ọrọ naa de ọdọ Ọga agba to n mojuto eto ẹkọ jale-jako ati akọwe ijọba ibilẹ Ilọrin West. Nigba ti wọn kan si mi, mo ni ko buru, ohun ti wọn ba sọ ni mo fara mọ. Nigba to jẹ pe ohun to wu u ni, ko yẹ ka ma gba a laaye.
O dupẹ lọwọ Gomina Abdulrahman Abdulrazaq fun ipese ẹkọ ọfẹ fawọn talika ati fun atunṣe ileewe naa.