O n rugbo bọ! Awọn aṣofin kọju ija si Sanwoolu

Faith Adebọla, Eko

 Bi iyanju ko ba tete waye lori ọrọ to n lọ lọwọ laarin awọn aṣofin ipinlẹ Eko, atijọba, afaimọ lawọn aṣofin naa ko ni i tẹsẹ bọ ṣokoto kan naa pẹlu Gomina Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu atawọn ọmọọṣẹ rẹ kan ti wọn ni iyansipo wọn ko bofin mu, eyi to mu kawọn aṣofin naa paṣẹ pe kijọba da sisan owo-oṣu wọn duro lẹyẹ-o-sọka, ki wọn si gba iwe iyansipo wọn kuro lọwọ wọn lẹsẹkẹsẹ.

Aṣẹ yii waye nibi apero awọn aṣofin naa lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹrin, ọdun yii, lasiko ijokoo wọn ni gbọngan apero wọn to wa ni Alausa, Ikẹja, niluu Eko.

Bakan naa ni wọn tun paṣẹ pe ki Olori awọn oṣiṣẹ ọba nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Hakeem Muri-Okunọla, yọju sawọn lati waa ṣalaye bọrọ akiyesi iwa titẹ ofin loju tawọn ri naa ṣe jẹ, wọn si tun paṣẹ pe ki Oluṣiro-owo agba fun ipinlẹ Eko, Ọmọwe Abiọdun Muritala, Kọmiṣanna to n ri sọrọ awọn ẹka ileeṣẹ ọba, Abilekọ Ajibọla Pọnnle, ko awọn iwe wọn kan wa, kawọn mẹtẹẹta waa ba awọn foju rinju lori ẹsun ọhun.

Ọnarebu Noheem Adams, to n ṣoju awọn eeyan Eti-Ọsa Kin-in-ni lo kọkọ mu ẹsun wa pe aṣa buruku kan ti n ṣe bii ere bii ere di baraku fun gomina ipinlẹ Eko, lati maa yan awọn eeyan sipo lai gba iwaju awọn aṣofin naa kọja gẹgẹ bofin ṣe la a kalẹ, o lọpọ awọn ti wọn gbọna ẹburu bẹẹ depo ni wọn ti n gba owo-oṣu ati ajẹmọnu, ti wọn si ti kọwe igbani-siṣẹ fun wọn lọna aitọ.

O ni tiru aṣa yii ba n lọ bẹẹ, o le sọ ilana ojuṣe awa aṣofin di yẹpẹrẹ. Fun apẹẹrẹ, lati ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2022, ni wọn ti yan Auditor-General sipo, oni si ni ọjọ kọkanla, oṣu Kẹrin, ọdun 2023.

Bi Ọnarebu Noheem ṣe n pari ọrọ rẹ ni Ọnarebu Ademọla Kasumu, to n ṣoju awọn eeyan Ikẹja naa sọ pe awọn iyansipo ti wọn n sọrọ rẹ ọhun ko bofin mu, ko si le rẹsẹ walẹ loju ofin, tori ẹ, o rọ ile naa lati pa a laṣẹ kawọn owo ti wọn ti na lawọn ẹka ileeṣẹ tọrọ kan ati owo-oṣu ti wọn ti san fawọn oṣiṣẹ ti iyansipo wọn lodi ọhun di dida pada sapo ijọba ni kiamọsa.

Ọnarebu Victor Akande sọ ni tiẹ pe iwa aibofinmu yii ko ṣẹṣẹ maa waye, o niru ẹ ti waye lasiko ti gomina ṣe iyansipo lẹka eto idajọ, lai fọrọ lọ ileegbimọ aṣofin Eko.

Ọnarebu Sa’ad Olumọ koro oju si bi alabọrun aṣa naa ṣe ti fẹẹ dẹwu fun ileeṣẹ gomina Eko.

Bakan naa Aṣofin Desmond Elliot ati Fẹmi Saheed lati Koṣọfẹ, kin gbogbo awọn to sọrọ ṣaaju lẹyin.

Lopin ijiroro, Abẹnugan Mudaṣiru Ọbasa, sọ pe oun fara mọ ero ati ọrọ tawọn ẹlẹgbẹ oun sọ pata, o si fountẹ jan awọn aba ti wọn mu wa pe ki awọn tọrọ kan naa yọju sawọn aṣofin lẹyẹ-o-sọka, bẹẹ lo ni ki wọn da owo-oṣu atawọn inawo mi-in lawọn ẹka ileeṣẹ naa duro na.

Leave a Reply