Ọpẹ o, lẹyin ọpọlọpọ ọdun to ti n wa ọmọ, Biọla Eyinọka bimọ ọkunrin

Jọkẹ Amọri

Bi wọn ba gẹṣin ninu arẹwa oṣere ilẹ wa nni, Abiọla Adebayọ, ti gbogbo eeyan mọ si Biọla Eyinọka, tọhun ko ni i kọsẹ. Eyi ko sẹyin iroyin ayọ to wọle idile naa lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin, ọdun yii.

 Iroyin ayọ naa si ni pe oṣere naa bi ọmọkunrin lantilanti. Funra rẹ lo gbe e sori Instagraamu rẹ pe ki gbogbo aye ba oun yọ, ki gbogbo aye ba oun dupẹ. Lẹyin gbogbo igbiyanju lati loyun lọna ti oloyinbo (IVF), iyẹn gbigba ẹyin tọkọ-tiyawo papọ, ti ko ṣee ṣe, laipẹ yii ni Ọlọrun mu ko ṣee ṣe fun oun, ti oun si bi ọmọkunrin kan.

Biọla ṣalaye pe, ‘‘Lẹyin ọpọlọpọ igbiyanju lati loyun nilana oyinbo (IVF), ta a tun gbiyanju pe ki ẹni kan ba wa gbe oyun naa, ti ko si tun bọ si i, ti igbiyanju ki eeyan kan tun ba wa gbe oyun naa tun fori sanpọn lẹẹmeji laarin ọdun meji, Ọlọrun fi ẹbun ọmọkunrin kan ta emi ati ọkọ mi lọrẹ nipasẹ ẹni kan to ba wa gbe oyun naa, ti ọmọ yii si jẹ ọmọkunrin.

 ‘‘Ninu gbogbo ohun ti a la kọja yii, Ọlọrun dara si wa gidigidi, a si dupẹ lọwọ Rẹ fun ẹri rere yii. A dupẹ o, Baba.

‘‘Ki Ọlọrun bukun dokita wa. Ki Ọlọrun bukun obinrin to ba wa gbe oyun naa.

Igba ọtun lo wọle yii

Kaabọ o, ‘TA’

‘‘Mo fẹ ki ẹ foju sọna fun irinajo mi lori bi wọn ṣe ba mi gbe oyun ọmọ naa.  Inu mi yoo dun lati pin iriri yii pẹlu awọn to ṣi n woju Ọlọrun fun ọmọ. Ki Ọlọrun gbọ adura gbogbo awọn ti wọn n woju Ọlọrun fun ọmọ’’.

Latigba ti Biọla ti gbe ọrọ yii sori ikanni rẹ ni gbogbo awọn oṣere ẹgbẹ rẹ, awọn ojulumọ, afẹnifẹre ti n ki i ku oriire, ti wọn si n gbadura fun iya ati ọmọ tuntun naa.

   Lara awọn oṣere to ti ki Biọla ku oriire ni oṣere-binrin to fi orileede Amẹrika ṣebugbe nni, Tawa Ajiṣefinni. Lati ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin yii, loṣere naa ti gbe e sori Instagraamu rẹ pe bi eeyan ba gẹṣin ninu oun lasiko yii, ko ni i kọsẹ. Bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan n ki i ku oriire, ko sẹni to mọ ohun to tori rẹ kọ ọrọ yii.

Afi laaarọ ọjọ Isẹgun, Tusidee, ti oṣere to lẹnu daadaa naa gbe e sori Instagraamu rẹ pe ‘A bimọ ooooooo. Emi lọlọpẹ. Ẹ ba wa yọ o. Ku oriire o, ololufẹ mi. Ọlọrun a ba wa wo o, aa da  si fun wa. Inu mi dun gidigidi.’’

Bakan naa ni Toyin Adewale naa ki oṣere naa pe, ‘Oluwa ṣeun oooooo, ayọ abara tintin. Abiọla, mo ba ẹ yọ, ayọ yii a ba ẹ kalẹ. Oluwa aa wo o, aa da a si fun wa.

Awọn oṣere mi-in to tun ki Biọla Eyinọka ni Ronkẹ Odusanya, Wumi Toriọla, Aiṣaha Lawal, Fathia Balogun, Mide Abiọdun ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun 2021, ni oṣere yii ati ọkọ rẹ, Oluwaṣeyi Akinrinde, ṣegbeyawo.

Leave a Reply