O Soju Mi Koro

Alagbara lanaa da: Oshiomhole to fẹẹ gbẹsan

Nigba ti Ọlọrun ba fun ni lagbara, ko si ohun to dara bii ka mọ pe Ọlọrun lo fun ni lagbara naa, o si le gba a nigbakugba to ba fẹ. Ohun ti eyi fi dara ni pe bi a ba ti n ranti ọrọ naa bayii, yoo ṣoro lati ṣi agbara ọhun lo, bi a ko ba si ṣi agbara lo, agbara ti Ọlọrun fun ni ki i bọ lọwọ ẹni. Bi eniyan ba ranti Adams Oshiomole, alaga ẹgbe oṣelu APC tẹlẹ, yoo mọ pe iṣoro gidi ni fun ẹda lati gun oke, ṣugbọn laarin ka diju ka la a, tọhun le ja bọ lori oke giga naa, ti yoo si ba ara rẹ nilẹ patapata. Lọsẹ to kọja lọhun-un, Oshiomole ni alaga APC, pẹlu agbara nla lọwọ rẹ, ti awọn gomina bii ogun si n wari foun nikan; awọn ọlọpaa oriṣiiriṣii lẹyin rẹ, aṣẹ to ba si fẹ lo n pa. Ṣugbọn nitori o ṣi agbara naa lo, kia lo ja bọ lati ori oke giga. Oun lo fi gomina to wa lori oye ni ipinlẹ Edo jẹ, oun lo mọ bi Obaseki ti di gomina. Ṣugbọn ko pẹ ti ija fi de laarin wọn, o si da bii pe ẹni to fi sipo naa ko mọ oore, tabi pe tọhun fẹẹ da a. N loun naa ba binu rangbọndan, to ni oun yoo ri i pe gomina naa ko pada sori oye mọ, n lo ba wa gbogbo ọna lati ri i pe ẹgbẹ APC rẹ ko fa ọkunrin naa kalẹ, wọn ni sabukeeti to gba nileewe ko daa. Bẹẹ, Oshiomhole funra ẹ lo n mu ọkunrin yii kiri lọdun mẹrin sẹyin, to n sọ fawọn ara Edo pe o mọwe, ori ẹ fẹrẹ da lu. Bi agbalagba ba pade ọmọ to ti n dọbalẹ ki i tẹlẹ loju ọna, ti ọmọ naa duro tandi, to si mura lati bu agbalagba naa ko ba a ja, agba to ba gbọn yẹ ko mọ pe o ni ohun ti ọmọde naa gboju le, o yẹ ko mọ pe o ni awọn alafẹyinti kan. Oshiomhole ko fura, ko mọ pe o yẹ ki oun fi ija fun Ọlọrun ja, ki oun jẹ ki Ọlọrun ba oun gbẹsan lara ẹni to ba dalẹ tabi ṣe aidaa oun. Kaka bẹẹ, o bọ ẹwu silẹ, o ni awọn yoo jọ na an tan bii owo ni. N lawọn alatilẹyin Obaseki ba jade. Eyi to ku, iregbe, wọn yọ Oshiomole nipo, Obaseki si ba ẹgbe PDP lọ. Ko si awawi kan nibẹ, ainisuuru, lagbaja-ṣẹ-mi-n-o-gbẹsan, lo ko ba Oshiomhole, ṣiṣi agbara lo lo ja a bọ nipo giga taye gbe e si. Eyi to buru ni pe ko tun ni i ri iru anfaani bẹẹ mọ lae, iyẹn lo ṣe yẹ ki gbogbo ẹni ba wa nipo fura. Ṣugbọn ọrọ awọn oloṣelu Naijiria ki i ri bẹẹ, wọn yoo ro pe lẹyin ti Ọlọrun da awọn tan, ko tun da ẹlomi-in mọ ni. Wọn yoo maa tẹlẹ hobahoba, wọn yoo maa mi họọ-họọ-họọ, awọn ẹni ti ko jẹ kinni kan ti wọn yoo maa pe ara wọn ni mejila. O n pẹ ko too bajẹ fun gbogbo oloṣelu agberaga; awọn ti wọn n nawo araalu, ti wọn si tun n jẹ gaba le wọn lori, awọn oniranu gbogbo!

 

Afaimọ lọkunrin Kogi yii ko ni i di alapata

Ti ẹ ba fẹẹ mọ oloṣelu alainikan-an-ṣe, tabi alaimọkan, Kogi ni ki ẹ maa lọ taara. Idi ni pe gomina to wa nibẹ, alaimọkan ti ko ni i gba pe oun ko mọkan ni. Idi niyẹn ti awọn ẹgbẹ oṣelu tabi ijọba wa ko ṣe n dara, nitori ọpọ awọn eeyan ti wọn wa nipo gomina tabi ipo alaṣẹ yii, ki i ṣe pe wọn ni igbaradi kan fun iṣẹ ti wọn waa ṣe yii, pupọ ninu wọn ko mọ idi ti wọn fi wa nibẹ, wọn ko mọ iṣẹ ti wọn waa ṣe. Ẹni kan ni yoo ti wọn si i pe ki wọn lọọ ṣe gomina, oun yoo nawo ẹ, oun yoo si lo agbara oun. Ki i ṣe pe ẹni ti wọn ti siwaju yii ni agbara tabi imọ kan, ko lero lati di gomina paapaa, ko si mọ ohun to fẹẹ ṣe to ba debẹ. Ti ẹ ba wo gomina Kogi yii finnifinni, iyẹn Yahaya Bello, ẹ o ri i pe awọn ti wọn ko mọ ohun ti wọn n ṣe nile ijọba, tabi itumọ ijọba ni. Oṣelu nikan ni wọn mọ, ohun ti wọn si mọ nidii oṣelu ko ju ki wọn maa ladii, ki wọn maa gbọn tẹle aṣaaju kan, ki wọn maa sọrọ didun si i leti, ki wọn maa tan an, ki iyẹn le ro pe wọn fẹran oun. Ni Kogi, nigba ti Koronafairọọsi yii bẹrẹ, Bello bẹre si i sọ fun gbogbo aye pe ko si Korona lọdọ oun, wọn fẹẹ fawọn taja lasan ni, awọn o si ni i gba. Ni bayii, ọpọlọpọ eeyan ti n ku ni Kogi, ẹni to si ku gbẹyin to di ariwo yii, Nasir Ajanah, Adajọ agba ipinlẹ naa ni. Ki oun too ku, Olori adajọ ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun ibilẹ, Ibrahim Shaibu Atadoga, naa ti ku. Awọn eeyan to lorukọ niyẹn o, awọn to ku ti ko lorukọ ko ṣee ka tan o. Ṣugbọn ko ma di pe ẹnikẹni yoo bu Bello, o jade, o ni oun ti pari iṣẹ, awọn gomina ẹgbẹ PDP mẹwaa lo n bọ ninu ẹgbẹ APC tawọn. Irọ lo n pa o, oun naa mọ pe irọ loun n pa. Ṣugbọn ohun ti yoo fi tan awọn ọga rẹ to yẹ ki wọn bu u pe o sọ ara rẹ di alapata, o n pa awọn ara Kogi bii ẹni pẹran niyẹn. Kaka ki wọn bu u, wọn yoo maa rẹrin-in si i, wọn yoo maa faye awọn eeyan ta kaiti ni. Ṣugbọn ta ni yoo ba Bello sọrọ, ko ma fiku Korona pa awọn ara Kogi o.

 

Ṣe bo yẹ kawọn oloṣelu Naijiria fi ti Ajimọbi yii ṣarikọgbọn ni

Nigba ti awọn oloṣelu ba n ṣe girigira kiri, Ọlọrun nikan lo mọ ibi ti laakaye wọn maa n gba lọ. Pupọ ninu wọn maa n ṣe bii ẹni ti ko ni i ku lae mọ ni o. Ẹmi ti ko ni i di ọla, yoo si maa da oṣu mẹfa, wọn yoo maa da ọdun mẹrin, pe ti lagbaja ba ṣejọba ẹ tan, lagbaja mi-in lawọn yoo tun fi sibẹ. Nigba ti eeyan ba ri Ajimọbi ninu fidio nigba ti aawẹ Ramadan n pari lọ, nibi toun ati awọn ẹbi rẹ ti n tunu, ati bo ṣe n fi gbogbo ara ṣere, ko sẹni ti yoo ro iku ro o lọdun mẹẹẹdogun sasiko yii, ṣugbọn bo ti wu Olọrun ni i ṣọla rẹ. Ko si ẹni to n ba ti awọn eeyan ti wọn ba lorukọ jẹ niluu, paapaa awọn oloṣelu yii jẹ, ju awọn ti wọn sun mọ wọn lọ. Awọn yii ki i sọ ootọ fun wọn, irọ oriṣiiriṣii ni wọn yoo si maa ba wọn pa faraalu. Awọn eeyan Ajimọbi gbe fidio jade, fidio atijọ, wọn ni tuntun ni, wọn lo ti gbadun, wọn ni ko sohun to n ṣe e mọ, wọn ni yoo gba ipo rẹ gẹgẹ bii adele alaga APC laipẹ. Ṣe nitori Ajimọbi lawọn eeyan yii ṣe n ṣe bayii tabi nitori ijẹkujẹ tiwọn. Ọkẹrẹ gori iroko bayii, oju ọdẹ da, wọn ti fi aimọkan ati eke pẹlu irọ pipa wọn din apọnle ara oku ọrun ku. Bẹẹ awọn naa yoo si ku o, wọn yoo si gbẹsan aburu wọn. Ki awọn oloṣelu wo ti Ajimọbi yii, ki wọn mọ pe giragira ti wọn n ba kiri yii ko debi kan bọ, ẹsẹ mẹfa lopin wọn. Wọn si fẹ wọn kọ, wọn yoo ju wọn si saree gbẹyin naa ni. Ajimọbi ti lọ, ko si sẹni kan ti yoo ri i mọ, afi loju ala nikan. Ki Ọlọrun dẹlẹ fun un, ko fori aṣiṣe rẹ gbogbo ji i, ki gbogbo ohun to fi saye ma si ṣe bajẹ lẹyin to ti lọ.

Leave a Reply