O tan! Ayu n lọ bi a ti kọwe rẹ lẹgbẹ PDP

Faith Adebọla

Akoko yii o rọgbọ fun oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, Alaaji Atiku Abubakar, latari bi emi-o-gba iwọ-o-gba to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ naa ṣe fẹẹ fa aburada ẹgbẹ ọhun ya, wọn lawọn alatilẹyin rẹ ti koro oju si bi Atiku ṣe ṣadehun fun Nyesom Wike, Gomina ipinlẹ Rivers, pe bo ba jẹ lile Iyorchia Ayu kuro nipo Alaga lo maa fopin si gbodo-n-roṣọ to n ti n waye lẹgbẹ oṣelu naa, oun ti gba, oun si ti fara mọ ọn, ki Ayu lọọ wabikan jokoo si na.

Adehun yii la gbọ pe o waye nigba ti Wike, ọkunrin to ti n kọrin ‘‘b’Arọni o wale, Onikoyi o sinmi ogun’’ lẹgbẹ oṣelu naa foju rinju pẹlu Atiku Abubakar niluu London, lorileede United Kingdom, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹjọ yii.

Yatọ si yiyọ Ayu nipo, lara adehun ti wọn jọ fẹnu ko le lori ni pe iha Guusu ilẹ wa, iyẹn agbegbe ti Wike ti wa, ni yoo fa alaga mi-in kalẹ, ati pe wọn gbọdọ fun Wike atawọn alatilẹyin rẹ lanfaani lati fa ẹni tọkan wọn ba fẹ kalẹ.

Wọn l’Atiku tun loun ti fara mọ ọn pe ki iha Guusu yan olori ileegbimọ aṣofin agba, iyẹn aarẹ awọn sẹnetọ, ki wọn si tun yan-anyan sawọn ipo adari kan nileegbimọ aṣofin, ti Atiku ati ẹgbẹ PDP ba ti jawe olubori ninu eto idibo gbogbogboo ọdun 2023 to n bọ yii.

Ṣugbọn ko daju, boya Atiku ṣadehun pẹlu awọn Wike pe saa kan ṣoṣo loun yoo lo nipo, tabi ko ṣe bẹẹ, tori lara ohun ti Wike atawọn tiẹ n beere ni pe ki oludije naa tọwọ bọwe pe oun ko ni i lo ju saa ọdun mẹrin akọkọ lọ toun ba bọ sipo aarẹ.

Wọn tun l’Atiku ti gba lati  fun awọn eeyan ti Wike ba fa kalẹ yan ipo minisita pataki, nigba tijọba Atiku ba gori aleefa.

Ṣe bu fun mi n bu fun ọ lọpọlọ n ke lodo, wọn lawọn igun ti Wike yii naa ti fọkan Atiku balẹ pe pẹlu adehun ati igbesẹ abẹwo rẹ ọhun, iduro o si, ibẹrẹ o si mọ, gbogbo atilẹyin ati igbarukuti to ba yẹ lawọn maa ṣe fun eto ipolongo ibo Atiku ati igbakeji rẹ, Ifeanyi Okowa, bawọn ṣe maa nawo lawọn maa nara pẹlu, ki ẹgbẹ oṣelu PDP le wọle ṣọ bii ekurọ, sipo agbara lọdun 2023.

Amọ ṣa o, ni ti iyọnipo Alaga wọn, Ayu, wọn lawọn mejeeji ṣadehun pe wọn o gbọdọ yọ baba naa niyọ iwọsi rara, ki ọrọ ma tun lọọ bẹyin yọ, wọn gbọdọ fẹsọ ṣe e ni, ati pe ki wọn wa ipo pataki mi-in fun un nigba tijọba PDP ba gori aleefa.

Latari awọn adehun yii, wọn lẹrin-in ayọ lo bọ lẹnu Wike ati Atiku niluu London, bawọn mejeeji ṣe fọwọ kọra wọn lọrun, bẹẹ lawọn gomina to wa pẹlu Wike, Ṣeyi Makinde tipinlẹ Ọyọ, Samuel Ortom tipinlẹ Benue ati Okezie Ikpeazu lati Abia, atawọn meji mi-in to tẹle Atiku lọ, naa di mọ ara wọn.

Bakan naa la gbọ pe tọtun-un tosi ti gba lati sinmi agbaja lati akoko yii lọ, wọn ni isoko-ọrọ-sira ẹni ati ibinu yoo rodo lọọ mumi lẹgbẹ oṣelu naa, eku yoo si bẹrẹ si i ke bii eku, tẹyẹ naa yoo maa ke bii ẹyẹ.

Tẹ o ba gbagbe, fun bii ọjọ mẹta ni Wike atawọn tiẹ fi gbalejo awọn oludije funpo aarẹ mẹta ọtọọtọ, bẹrẹ latori Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ti ẹgbẹ APC lọjọ Tusidee, Atiku lọjọ Wẹsidee, Peter Obi lati ẹgbẹ Labour, ti Ọbasanjọ ati Donald Duke sin lọ, lọjọ Tọsidee.

Ipa ti adehun Wike ati Atiku yii yoo ni lori ajọsọ rẹ pẹlu awọn oludije yooku lẹnikan o ti i le sọ bayii.

 

Leave a Reply