O tan! Ọba Sokoto binu si Buhari

Aderounmu Kazeem

Ẹgbe kan, Jama’atu Nasril Islam, ti Ọba  ilu Sokoto, Alhaji Sa’ad Abubakar, n dari ẹ ti sọ pe bi awọn janduku ajinigbe ṣe n kolu awon ileewe nilẹ Hausa ti wọn si n ji awọn ọmọ ko lọ yii ko ni oriire kan bayii to fẹẹ ko ba ilẹ Hausa bi ko ṣe idaamu ọjọ iwaju.

Ana ọjọ Aje, Mọnde, ni akọwe agba, Dr. Khalid Abubakar Aliyu, fi atẹjade ọhun sita lorukọ Ọba ilẹ Sokoto, Alhaji Sa’ad Abubakar, nibi ti Olori awọn Hausa yii ti sọrọ naa.

Ninu ọrọ ẹ lo ti sọ pe idaamu ti awọn janduku ajinigbe yii n da silẹ bayii nilẹ Hausa ko ni i ṣalai ṣakoba fawọn eeyan ibẹ, ati pe ojuna lati mu eto ẹkọ jo ajorẹyin ni yoo jẹ lọjọ iwaju.

Sultan ni ọpọ awọn obi ni ọkan wọn ko balẹ mọ lati fi ọmọ wọn sileewe, niwọn igba to jẹ pe niṣe lawọn ajinigbe yoo kan ya wọ ibẹ, ti wọn yoo si ko wọn lọmọ lọ, tijọba paapaa ko ni i rohun kan bayii ṣe si i.

 

Ọba ilẹ Sokoto tẹ siwaju pe, ohun ikaya lo jẹ bi awọn janduku ti ṣe kọlu ileewe Government Science Secondary School, ni Kankara, nipinlẹ Katsina lọwọ aṣalẹ ọjọ, Ẹti, Furaidee to kọja yii lasiko ti Aarẹ Miuhammad Buhari gan-an wa nipinlẹ ọhun.

O ni, ohun itiju lo yẹ ki eleyii jẹ fun Buhari, ki oun naa fi le mọpe eto aabo ijoba oun koo dara, abi nigba ti awọn ajinigbe tun waa n kogun ja a mọle lasiko to wa ninu ilu ẹ gan-an.

Bakan naa lo sọ pe asiko niyi fun un lati gbọ ohun ti awọn araalu n sọ kijọba ẹ si tete gbe igbesẹ lori bi yoo ti ṣe mu atunto gidi ba eto aabo orilẹ-ede yii, paapaa lori awọn alakooso to fi ṣe ọga ologun.

Siwaju si i, Sultan ni o to gẹẹ lori bi Aarẹ Buhari ṣe maa n tẹnumọ ọrọ kan naa ni gbogbo igba ti wahala ba ti ṣẹlẹ wi pe o ba oun ninu jẹ. O ki Buhari yee daro mọ, ohun tawọn eeyan n fẹ bayii ni ko wa bi wahala ikọlu oriṣiiriṣi ṣe n waye ni ilẹ Hausa yii yoo ṣe dopin, ki awọn ẹṣọ agbofinro ati alaabo si wa awọn ọmọ ti wọn ji ko yii ri.

Leave a Reply