Ọba Akiolu sọ fun oludije Labour to ṣabẹwo si i pe Sanwo-Olu ni yoo wọle ibo Eko

Monisọla Saka

L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni Ọba ilu Eko, Riliwan Akiolu, sọ fun oludije dupo gomina ipinlẹ Eko labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Gbadebọ Rhodes-Vivour, pe gomina to wa nipo, to tun jẹ oludije funpo gomina lẹgbẹ oṣelu APC, Babajide Sanwo-Olu, ni yoo wọle ibo ọjọ Satide yii.

Lori ẹrọ abẹyẹfo Twitter rẹ, ni Gbadebọ ti kọ ọ si pe, “Baba mi atawọn eeyan mi kọwọọrin pẹlu mi lonii, lasiko ta a lọọ ṣabẹwo ‘baba kẹ ẹ pẹ’, si ọba ilu Eko. Awa ọmọ Eko pataki maa n ṣapọnle, a si maa n wari fawọn ọba alaye wa, mo si n gbero lati ṣiṣẹ pẹlu wọn fun ipinlẹ Eko to daa ju bayii lọ”.

Ọba alaye to gboriyin fun oludije lẹgbẹ Labour ọhun fun bo ṣe jade sita lati dupo gomina, nitori pe o lẹtọọ lati ṣe bẹẹ sọ pe, ti Sanwo-Olu loun n ṣe lọjọkọjọ, ati pe oun ni yoo wọle ibo lọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta, ọdun yii.

Akiolu sọrọ yii lasiko ti Gbadebọ ati baba ẹ, Ọlawale, pẹlu awọn ikọ ipolongo ibo ẹ lọọ ṣabẹwo si ọba alaye naa ninu aafin ẹ to wa ni Iga-Iduganran niluu Eko.

Gẹgẹ bi ọba naa ṣe sọ, o ni Ọlọrun ti yan Sanwo-Olu lati dari ipinlẹ naa fun ọdun mẹrin mi-in.

Lai wo pe ọrọ naa le dun Gbadebọ to waa ki i sinu aafin ẹ lati ṣapọnle ẹ ati lati fi erongba ẹ han gẹgẹ bii ọkan ninu awọn to n dije funpo gomina l’Ekoo han, Ọba Akiolu sọ pe, “Sanwo-Olu lemi ti kede atilẹyin fun nitori mo nigbagbọ ninu rẹ, Ọlọrun gan-an si ti sọ pe Sanwo-Olu ni yoo wọle.

Ṣe o waa ri iwọ Gbadebọ, ọjọ iwaju ta a n wo yii ṣi dara. Ọlọrun ko ni i pa ẹ, ko si aburu ninu pe iwọ naa gbegba ibo pe o n dije funpo kan. Ọmọ mi ni gbogbo awọn ti wọn n dije dupo yii”.

Nigba to n mẹnuba awọn iṣẹ daadaa atawọn ohun meremere to ni ijọba Sanwo-Olu ti gbe ṣe lati bii ọdun mẹrin sẹyin, o ni asiko ti nnkan lọ jaijai nipinlẹ naa lo wọle ibo, eyi ko si di i lọwọ lati ṣiṣẹ ribiribi.

O ni, “Emi ki i ṣe ẹni to n ba buruburu feeyan pataki kan, bẹẹ ni mi o ki i ṣe alabosi. Gbadebọ, ọjọ iwaju rẹ ṣi dara, ki Ọlọrun da ẹmi rẹ si, ko sohun to buru ninu pe o gbegba ibo. Mo wa n bẹ ẹ pe ko o ma tẹti, tubọ gbiyanju si i, ma kaaarẹ ọkan lẹyin eyi, ṣugbọn gbagbaagba ni mo wa lẹyin Sanwo-Olu. Gbogbo ẹyin tẹ ẹ n dupo yii naa lẹ jẹ ọmọ fun mi. Mo wa n gba a laduura pẹlu aṣẹ to wa ninu aafin yii pe ki Ọlọrun ba wa yi ilu yii pada si daadaa. Ko si si bi mo ṣe le koriira awọn ẹya Ibo, nitori awọn ni wọn pọ ju ninu awọn ọrẹ to sun mọ mi ju”.

Bakan naa ni Akiolu tun gbadura pe ki Ọlọrun gbakoso lọjọ idibo, ki rogbodiyan ma si ṣe ṣẹlẹ. Ọba alaye naa waa rọ awọn olugbe Eko lati tu yaayaa jade waa dibo lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta, ọdun yii, ki wọn si ri i daju pe ohun gbogbo lọ nirọwọ rọsẹ, lai fa wahala kankan.

Leave a Reply