Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Olu ti Ayepe Ọlọdẹ, nijọba ibilẹ Guusu Ifẹ, nipinlẹ Ọṣun, Ọba David Ọlajide Omiṣore, Omigbade 1, ti waja.
Laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, la gbọ pe baba to bi Sẹnetọ Iyiọla Omiṣore naa darapọ mọ awọn baba nla rẹ.
Ọmọ aadọrun-un ọdun ni baba naa ki ọlọjọ too de.