Ọmọ ọdun mẹrinla to ji ọmọ ọga ẹ gbe l’Ekoo  bọ sọwọ ọlọpaa l’Ogun

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

 Ọmọ ọdọ ni wọn gba a fun, iyẹn Favour Iwuozor, ọmọdebinrin ọmọ ọdun mẹrinla to gbe ọmọ kerere dani yii, pe ko maa tọju ile tọju ọmọ, afi bo ṣe ji ọmọ ti wọn ni ko maa tọju gbe l’Ekoo, kọwọ too ba a ni Ṣagamu, ipinlẹ Ogun.

Ọjọ kẹta, oṣu kin-in-ni, ọdun yii, lọwọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun tẹ ẹ fun ẹsun jiji ọmọ gbe sa lọ.

Lọjọ kejilelogun, oṣu kejila, ọdun 2021, to pari yii ni Favour gbe ọmọ ọga rẹ yii jade ni Yaba, l’Ekoo, to si bẹrẹ si i fi ọmọ naa tọrọ baara lọwọ awọn eeyan.

Alaye to n ṣe fun wọn ni pe aburo oun ree, ara rẹ ko ya, awọn obi awọn si ti ku ninu ijamba ọkọ lọdun 2020, kawọn eeyan dakun ṣaanu oun koun le rowo tọju ọmọ ọdun meji ti ara rẹ ko ya naa.

Nibi to ti n tọrọ owo pẹlu ọmọ to han pe ara rẹ ko ya naa ni obinrin kan, Victoria Nwafor, ni ki Favour ati aburo ẹ jẹ kawọn lọ sile oun, oun yoo tọju wọn, lo ba mu wọn lọ sile rẹ ni Ṣagamu, o si bẹrẹ si i tọju wọn.

Nigba ti ara ọmọ ọdun meji naa ya tan latari itọju ti iya yii fun un, Favour lawọn ti fẹẹ maa lọ, oun fẹẹ gbe aburo oun naa lọ siluu awọn nipinlẹ Imo.

Ohun to sọ yii lo mu ara fu iya to gba wọn sọdọ, nitori o ro o pe ọjọ ori Favour kere si ohun to fẹẹ ṣe, bo ṣe lọọ sọrọ naa fawọn ọlọpaa niyẹn.

Awọn agbofinro Ṣagamu waa mu Favour, o si ṣalaye fun wọn pe ọmọ ọdọ loun n ṣe lọdọ iya ọmọ ọdun meji naa. O ni lati ọjọ kọkandinlogun, oṣu kejila, ọdun 2021, loun ti gbe ọmọ naa kuro nile.

O ni ṣọọṣi lawọn wa toun ti lọọ gba ọmọ naa lọwọ olukọ ileewe ọjọ isinmi to n kọ wọn, nigba to jẹ tiṣa to n kọ wọn nibẹ mọ pe oun lọmọ ọdọ iya ọmọ naa lo ṣe yọnda ẹ foun.

Ọmọ ọdun mẹrinla yii tẹsiwaju pe owo mọto toun yoo wọ de ipinlẹ Imo pẹlu ọmọ ọlọmọ naa loun n wa toun fi bẹrẹ si i tọrọ owo lọwọ awọn eeyan, pẹlu irọ nla toun n pa fun wọn, ko too di pe iya to n gbe ni Ṣagamu mu oun ati ọmọ naa wale.

Ọga ọlọpaa Ogun, CP Lanre Bankọle paṣẹ pe ki wọn kan sawọn obi ọmọ to ji gbe, ki wọn si taari ẹjọ yii pada siluu Eko ti ọmọ ọdun mẹrinla yii ti lufin

Leave a Reply